Ààrẹ Tinubu rọ gbogbo olórí iléeṣẹ́ ọmọogun àti ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà lóyè

Oríṣun àwòrán, Bolatinubu/twitter
Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti fi ẹyin gbogbo awọn adari ẹka ọmọogun lorilẹede Naijiria ti bayii.
Bakan naa lo tun fi ẹyin ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ati olori ileeṣẹ aṣọbode ti pẹlu.
Lẹsẹkẹsẹ si ni aarẹ kede awọn adari tuntun fun ileeṣẹ ọmọogun, ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ aṣọbode.
Mallam Nuhu Ribadu ni Olubadamọran agba fun eto abo, yoo maa gba iṣẹ lọwọ Ọgagun agba Babagana Monguno.
Ọgagun agba C.G. Musa ni olori tuntun fun ileeṣẹ ọmọogun apapọ lorilẹede Naijiria.
Ọgagun agba T.A. Lagbaja ni olori tuntun fun ileeṣẹ ọmọogun ori ilẹ.
Ọgagun oju omi E.A. Ogalla ni ọgagun agb tuntun fun ileeṣẹ ọmọogun oju omi.
Ọgagun ofunrufu AVM H.B. Abubakar ni olori tuntun fun ileeṣẹ ọmọogun ofurufu
DIG Kayọde Ẹgbẹtokun ni ọga ọlọpaa tuntun lorilẹede Naijiria nigba ti ọgagun EPA Undiandeye yoo jẹ olori ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ alaabo Naijiria, DI.

Oríṣun àwòrán, Bashirahmad/twitter
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun yan Adeniyi Bashir Adewale gẹgẹ bi adele ọga agba ileeṣẹ aṣọbode Naijiria.
Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Naijiria tun ṣe afikun awọn amugbalẹgbẹ lẹ pẹlu mejẹrin miran.
Hadiza Bala Usman ni olubadamọran pataki lori eto ilana ijọba (Policy Coordination).
Hannatu Musa Musawa ni olubadamọran pataki lori ọrọ aṣa ati idaraya .
Sẹnetọ Abdullahi Abubakar Gumel ni oluranlọwọ agba lori ọrọ ile igbimọ aṣofin agba.
Họnọrebu Ọlarewaju Kunle Ibrahim ni oluranlọwọ agba lori ọrọ ile igbimọ aṣojuṣofin












