CBN gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí gbèdéke iye "dollar" tóo lè kó sínú akoto owó ilẹ̀ òkèrè rẹ

Aworan owo Naira ati Dọla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Banki apapọ lorileede Naijria, CBN, ti mu iyipada ba ofin to de iye owo dọla ti araalu le ni ninu akanti owo ilẹ okere wọn taa mọ si domicilliary account.

Ninu ilana tuntun yii awọn to ba ni akanti iru eleyi ko ni ni idiwọ kankan lati san owo tabi gba owo jade ninu akanti wọn.

Ni bayii wọn lanfaani lati ko owo dọla ti ko ju ẹgbẹrun mẹwaa sinu akoto owo wọn lojumọ kọọkan leyi to si jẹ pe tẹlẹ, iroyin ni ko ju ẹgbẹrun marun lọ eyi to jẹ ko nira fun awọn ara orilẹede mii bii Naijiria lati lee fi owo dọla wọn ṣe nnkan pupọ.

Bẹẹ naa ni wọn le san dede owo yii sinu akanti owo ilẹ okere wọn lojumọ lai si idiwọ.

Ọga agba ni ẹka ibaraẹnisọrọ ileeṣẹ banki apapọ Dr Isa Abdulmumin lo fi ọrọ yi lede ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku.

Atẹjade naa sọ pe ''awọn to ba ni akanti owo ilẹ okere ko ni ni idiwọ kankan fun wọn lati lo owo to wa ninu akoto wọn. Awọn to ni akanti yi ni aaye lati lo $10,000 lojumọ tabi owo to ṣe dede rẹ nipa oju opo ifowo ranṣẹ''

O tun sọ pe awọn ile ifowopamọ yoo pese iroyin to peye fun banki apapọ lori ''oun ti ẹni yi fẹ lo owo naa fun''

Ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch ti ṣaaju jabọ loṣu Karun un ọdun 2021 pe awọn ile ifowopamọ ti gbe gbedeke lori aṣunwọn onibara wọn lori iye owo ti wọn le gba wọle sinu akoto owo wọn ti ilẹ okere.

Nigba naa lọhun, a gbọ pe atẹjade kan ti Punch lawọn foju ri fihan pe '' laarin oṣu kan $5,000 pere ni onibara to ba ni iru akanti yi le lanfaani lati gba tabi san wọle sinu akoto owo rẹ''.

Ki lawọn araalu n sọ lori igbesẹ yi

Loju opo Twitter awọn ọmọ Naijiria ni paapa awọn ọdọ n gboṣuba fun igbesẹ yii amọ wọn ni o ku ti banki naa le ṣe lori iyipada eto ọrọ owo ilẹ okere.

Awọn kan mẹnu ba mimu alekun ba iye owo ti alabara ile ifowopamọ le fi ra nkan ninu kaadi atm akanti Naira rẹ.

Saaju asiko yi,ogun dọla pere ni awọn eeyan lanfraani lati fi ra nkan ninu akanti wọn pẹlu kaadi ATM ti ile ifowopamọ fun wọn.

Pupọ ni igbesẹ yi dara ṣugbọn ki wọn jẹ ki onibara banki le fi owo ra nkan pẹlu kaadi yi.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2