Ìròyìn òfegè ní pé 'transfer' owó kò ní lọ mọ́ láti òní lọ– CBN

Oríṣun àwòrán, others
Ajọ banki apapọ lorilẹede Naijiria CBN ni ki awọn araalu yago fun iroyin ẹlẹjẹ kan to ti gba ori ayelujara pe awọn yoo sa isẹ silẹ lonii Ọjọ kẹtalelogun, ọsu keji ọdun, ki awọn araalu si igbinyanju lati lọ gba ọpọlọpọ owo sọwọ.
CBN gbe ikede naa jade lori opo ayelujara Twitter rẹ, to si rọ awọn eeyan lati fi aye silẹ fun iroyin ifege naa lati da wọn riboribo.
Ibẹrẹ ọsẹ yii ni iroyin ofege naa bẹrẹ si ni ma tan kakiri opo ayelujare Whatsapp, ti ọpọ awọn eeyan si pin kiri, eyi to fi mu ki ọpọlọpọ maa sa kiri lori bi wọn yoo ṣe ti owo gba sọwọ.
Iroyin ofege naa tẹsiwaju pe yoo nira fun awọn araalu lati fi owo ransẹ si arawọn nitori ajọ banki apapọ Naijiria yoo dasẹ silẹ lati Ọjọ kẹtalelogun di Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji ọdun 2011.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Èmi gan an tí mo jẹ́ gómìnà kò ní naira tuntun lọ́wọ́, gbogbo wa lọ̀rọ̀ Emefiele yìí bá-Adeleke

Oríṣun àwòrán, @Adeleke
Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe atolowo ati mẹkunu lọrọ inira ọwọngogo owo naira tuntun ba lorilẹede Naijiria.
Gomina Adeleke ni oun gan gẹgẹ gomina ko ni owo tuntun ti a n sọ yii lọwọ.
Adeleke sọrọ yii lasiko to pe ipade pẹlu awọn adari ẹka banki CBN ni ipinlẹ Ọsun lori ọwọngogo owo naira to n ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria finra bayii.
“Awọn owo tuntun yii ko si nigboro, koda emi gan gẹgẹ bi gomina ko ni owo naira tuntu yii lọwọ. Ẹ ri pe nigba ti emi ti mo jẹ gomina gan ko ri owo tuntun naa melomelo lawọn.ẹkunu nilu ṣe fẹ ri i.
“ A ko gbọdọ fi ọbọ lọ awọn eeyan wa nitori ifọwọsowọpọ wọn o. Ojuṣe gbogbo awa ti wọn dibo ya at’awọn ti a yan si ipo iṣejọ ni lati bo rin itura araalu “

Adeleke ni o yẹ ki awọn alasẹ banki apaọ CBN o salaye ohun gan to n ṣẹlẹ gan boya owo naa ko to ni tabi awọn banki kan lo n koo pamọ.
O ni gbogbo irinṣẹ ti ofin fun oun gege bi gomina ipinlẹ ọsun loun ti n lo lati fi rii daju pe alaafia jọba ni ipinlẹ Ọsun, ati lati rii pe irufẹ awọn iwọde to n lọ kaakiri ko waye ni ipinlẹ Ọṣun
“Lootọ awọn eeyan mi ni suuru, sibẹ a ko gbọdọ rẹ wọn jẹ. idi ti mo fi pe ipade yii niyi. Ki lo fa ọwọngogo naira? Ṣe awọn ti ẹ ko sita ko to ni abi o kere?
ti da sẹria fawọn banki lori ọrọ ọwọ gogo owo tuntun yii - CBN

Nigba to n fesi, adari ẹka banki CBN ni ipinlẹ Ọṣun, Oluyẹmi Adeyẹmi sọ pe banki apapọ naa ti n gbe igbesẹ lati dẹkun ọwọngogo naa ati pe wọn ti gbe igbesẹ ibawi lori awọn banki to b an ko owo naa pamọ.
“Ni iha tiwa, a ti n gbe igbesẹ ki owo tuntun naa le pọ nigboro. Bakan naa ni CBN tun ti kọ iwe ibawi sí awọn banki kan. Mo fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe a n ṣiṣẹ karakara lti rii pe owo naa wa larọwọto araalu.”












