“Mo bú sẹ́kún nígbà tí Dókítà sọ fún mí pe àwọn fẹ́ yọ kíndìnrín mi - Ọkùnrin tí Ekweremadu gbé lọ London jẹ́rìí nílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọmọ Naijiria kan to n ṣe katakara ti wọn gbe lọ si ilu London ti sọ fun adajọ pe o ya oun lẹnu nigba ti Dokita sọ fun oun pe wọn fẹ yọ Kindinrin rẹ.
Ni ile ẹjọ naa to wa ni Old Bailey, oloṣelu ọmọ Naijiria kan to jẹ ẹni ọdun Ọgọta ti n sọ ṣaaju pe oun ko ru ofin to wa nipa imuniṣẹru.
Ekweremadu n foju wina ẹsun pe o gbe ọdọ kan ẹni ọdun mọkanlelogun lọ si United Kingdom lati fun ọmọ tirẹ obinrin, Sonia ni Kindinrin rẹ.
Iyawo rẹ, Beatrice to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati ọmọbinrin rẹ Sonia ẹni ọdun marunlelogun to fi mọ asugba wọn, Dokita Obina Obeta ẹni aadọta ọdun naa sọ pe awọn ko lọwọ ninu ṣiṣe eto irinajo arakunrin naa lọ si ilẹ Britain pẹlu erongba lati ṣamulo rẹ nilokulo.
Ẹwẹ, agbẹjọro ijọba sọ pe Ekweremadu san owo fun awọn oniṣowo kan ni ọpọlọpọ owo Pọun lati ba a wa eeyan to lee yọnda Kindinrin rẹ ni Naijria ki wọn si ṣeto bi wọn yoo ṣe yọ ọ nilẹ Britain.
“Wọn jẹ gaba lori mi”

Oríṣun àwòrán, Ekweremadu/Facebook
Ọdọkunrin naa sọrọ pe “wọn n dari oun” ti wọn si ni ki oun parọ pe oun jẹ ibatan awọn Ekweremadu ṣaaju akoko ti yoo lọ si ile iwosan Royal Free Hospital ni North London ninu Oṣu Keji ọdun 2022. Eyi lo sọ fun adajọ.
Ile ẹjọ naa gbọ nigba ti o ni dokita sọ fun oun pe iṣẹ abẹ yiyọ kindinrin ni wọn wa fun pe “o ya oun lẹnu”.
“Mo bu sẹkun nigba ti o sọ fun mi nipa rẹ. Mo sọ fun un pe mi o mọ ohunkohun nipa yiyọ kindinrin,” ile ẹjọ gbọ lẹnu rẹ.
Ẹwẹ, latari pe wọn wo ọjọ ori rẹ ati pe ko ni imọ nipa ilana naa, Dokita meji lati ile iwosan Royal Free Hospital sọ pe ki wọn ma ṣe jẹ ki iṣẹ abẹ yiyọ kindinrin naa waye.
Ẹwẹ, latari pe wọn wo ọjọ ori rẹ ati pe ko ni imọ nipa ilana naa, Dokita meji lati ile iwosan Royal Free Hospital sọ pe ki wọn ma ṣe jẹ ki iṣẹ abẹ yiyọ kindinrin naa waye.
Pẹlu aridaju to fihan latinu fidio kan, ọdọkunrin ọmọ Naijiria naa sọ fun adajọ pe oun dagba ni ilu kekere kan ti ko ni ina tabi omi.
O lọ si ilu Eko nigba to wa lọmọdun mẹẹdogun lati lọ ṣiṣẹ pẹlu aburo baba rẹ kan to n ta eroja foonu ni ọja.
Lẹyin ọdun mẹfa ni Dokita Obeta ẹni ti wọn juwe gẹgẹ bi oṣiṣẹ fun Ọgbẹni Ekweremadu fun un ni anfani lati wa rinrinajo lọ si London.
Ọjọ akọkọ to pe Dokita naa, nnkan ṣoṣo to sọ fun un ni nipa iṣẹ.
“O ni ki n ma sọ fun ẹnikẹni pe mo n bọ wa si UK.”
Lẹyin ti gbogbo ilana ati rinrinajo rẹ to fi mọ gbigba iwe irina lọ si London yọri si rere, o tẹkọ ofurufu leti.
Nibi to ti n jẹun ni wọn ti sọ fun un pe ko wọ aṣọ to si lọ pade arabinrin kan ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi Sonia Ekweremadu ninu ile ẹjọ.
Sonia Ekweremadu ni iṣoro kindinrin eyi to nilo piparọ. Ohun ti wọn sọ fun ile ẹjọ ree.
Awọn mejeji ya fọto kan papọ eyi ti wọn fi sọ fun ile ẹjọ pe wọn kan fi dibọn pe wọn mọ ara wọn ri.
Pẹlu ipinu lati ma pada yọ kindinrin rẹ, ọdọkunrin naa fi aridaju han pe dokita meji tun ṣe ayẹwo oun ni ile Dokita Obeta to si tun fi ẹsun kan pe wọn ni ki oun maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọmọ ọdọ ti wọn ko si san owo fun oun.
“Mo sa kuro nile”
Ọdọkunrin naa ni oun sa kuro nile to si bẹrẹ si ni sun kiri ibikibi to ba ri. O rin kiri igboro London fun ọjọ meji.
Lakotan, o ni otutu naa pọ jọjọ. “Otutu naa fẹrẹẹ pa mi lọjọ naa. Torinaa ni mi o ṣe ni ọna mii”.
O wọ inu agọ ọlọpaa kan ni Staines, eyi si lo mu ki awọn ọlọpaa ṣe iwadii to wa mu ki igbẹjọ yii bẹrẹ.
Agbẹjọro to duro fun Dokita Obina Obenta ti bẹrẹ ayẹwo kikun, igbẹjọ naa si tẹsiwaju.














