Gbẹgẹdẹ gbiná! Olùdarí àgbà ilé ìwòsàn kó sọ́wọ́ Ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó ń ta ẹ̀yà ara aláìsàn

Dokita ileewosan ijọba ni Kaiama

Oríṣun àwòrán, Kwara State Police

Ileeṣẹ ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Kwara ti fi oju oludari ile iwosan ijọba àpapọ̀ to wa ni agbegbe Kaiama ni Ilorin latari ipaniyan ati yiyọ ẹ̀yà ara eniyan.

Iroyin sọ pe ni ọdun to kọja, awọn Aláṣẹ ri oku obinrin meji to ti jẹrà ti wọn ti ń wa ti wọn si fẹ̀sùn kan pe oludari ileewosan naa lo sin oku wọn pamọ si ibojì ikọkọ kan to ni ninu ọfiisi rẹ.

Ibi ti àṣírí Dokita ọhun to jẹ ọmọ ijọba ìbílẹ̀ Offa ni Ìpínlẹ̀ Kwara ti tu ni bi wọn ṣe fi ẹsun kan an pe o pa awakọ ero kan, Emmanuel Yobo Agbovinure.

Wọn ni pe ni Ìpínlẹ̀ Edo lo ti pa Emmanuel to sì ju oku rẹ si ilu Otofure ni opopona Benin si Eko to si sá lọ pẹlu ọkọ dereba naa.

Dokita nìkan kọ lo n da ṣe iṣẹ ipaniyan yìí - Ọlọpaa

Ileewosan ijọba ni Kaiama

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Komisọna Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Kwara, Paul Osama sọ̀rọ̀ nigba ti wọn n foju afurasi ẹni ọdun merindinlogoji naa han ni agọ wọn ni Ogunjọ Ọjọ́ Aje, Oṣù Keji pe Ileeṣẹ awọn n ṣe iṣẹ gidi lati fi ofin mu awọn ọmọ ẹgbẹ́ ikọ Dokita naa ti wọn jọ n lọwọ ninu ẹsun yii.

Gẹgẹ bi ọga Ọlọpaa ṣe sọ ọ, afurasi naa maa n fun awọn to fẹ lo loorun ti ọpọlọpọ wọn si jẹ obinrin ko to pa wọn.

Komisona Paul Odama fi kun un wipe wọn fi ẹsun kan afurasi ọhun pe o maa n pa awọn eniyan ti yoo tun sin wọn, bẹẹ si ni o n pa awọn mii lati yọ ẹ̀yà ara wọn.

Ọgbẹni Odama tun fi kun un pe afurasi ọhun ti kọ́kọ́ pa awọn kan ni Ìpínlẹ̀ Edo ko to pa awọn ti Ìpínlẹ̀ Kwara ti orebinrin rẹ si wa lara wọn.

Orúkọ awọn ti Ọlọpaa gbe sita ti ẹmi wọn ti ọwọ Dokita naa bọ:

Ileeṣẹ Ọlọpaa ti ṣe agbejade awọn oloogbe to ti ti ọwọ oludari agba ileewosan naa bọ gẹgẹ bii:

- Olanipekun Ifeoluwa Ibikun,

- Nafisat Halidu,

- Abubakar Malam Abubakar

Ati obinrin kan ti wọn ko mọ orukọ rẹ.

Bakan naa, wọn tun ba oriṣiriṣi nnkan to ji lọwọ rẹ bii ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry LE. Reg. No.: WSN 494 AA, Baagi apamabiya obinrin alawọ dudu atu alawọ pinki mii, foonu Infinix, foonu Techno, irun wiigi obinrin, iborun obinrin, awọtẹlẹ obinrin kan ati ike ikodọti si.

Ni ọjọ Kẹta Oṣu Keje ọdun 2022, Ọgbẹni Kuktar Opeyemi kan lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa “F” Division, Ilorin pe oun woye pe awọn ko ko firi ọkan lara awọn aladugbo oun ti orukọ rẹ jẹ Ifeoluwa, ati ọkọ rẹ mọ nile lati ọjọ Kẹrinlelogun Oṣu Kẹfa.

“Nigbati iwadi n lọ lọwọ nipa obinrin naa to dawati, eeyan kan wa fi ẹjọ sun pe wọn ri oku arabinrin ọdọbinrin kan ninu igbo lẹgbẹ ọna pẹlu apa ifarapa nla lori rẹ ati ẹjẹ loju rẹ.

Iwadii lo pada fihan pe Ifeoluwa Olaonipekun ti wọn n wa yẹn gaan ni eeyan kan ti pa to ju sinu igbo ni agbegbe Alagba”.

Bakan naa lo tẹsiwaju pe “iwadii fihan pe wọn ri Ifeoluwa kẹyin pẹlu pẹlu Adeyemi kan.”

Ohun to wa ṣokunfa didawati Ifeoluwa ni agbegbe Tanke amọ ti wọn tun lọ ri oku rẹ ni Alapa pe fun ifura pe Dokita naa mọ ohun kankan nipa Arabinrin naa to di awati.

Bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n wa Dokita naa ni iroyin wọle pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ipinlẹ Edo ti gba Dokita naa mu latari pe o lọwọ ninu ẹsun ipaniyan mii.

‘Afurasi jẹwọ pe oun pa awọn eeyan lootọ’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lasiko ti wọn n fi oju awọn afurasi ọdaran han lagọ ọlọpaa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ṣalaye bi afurasi Dokita naa ṣe ṣe awọn iṣẹ aburu to ṣe ọhun.

“O jẹwọ pe oun pa Ifeoluwa nipa fifi oolu kan lu u lori to si ju oku rẹ sinu igbo Alapa.

“Bakan naa lo tun jẹwọ pe oun ti ṣaaju fi oogun orun kun Abubakar Malam Abubakar kan lorun lati le ji i gbe, pa a ati Nafisat Halidu kan to jẹ oṣiṣẹ kongila ni ileewosan ijọba apapọ to wa ni Kaiama o si gbe oku rẹ pamọ sinu ibi ikodọti si to tun ko simẹnti bo inu ikodọti si ọhun, o gbe e pamọ sinu yara ikẹrupamọ si kan ninu ileewosan naa to si mu kọkọrọ ibẹ lọwọ.

“Lafikun, o tun jẹwọ pe oun pa arabinrin kan ti wọn ko mọ to si sin oku rẹ sinu ile ikẹrupamọ si ti ileewosan naa.

“O ṣalaye pe wọn tan oun sinu iṣẹ katakara ẹya ara eniyan yii ni nipasẹ afurasi mii ti wọn ko tii mọ.

Iwadii abẹle kan ti n waye lati tu aṣiri awọn iwa ipaniyan mii ti afurasi naa atawọn akẹgbẹ rẹ ti ṣe.”

Ẹwẹ, Ọga ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe Adeyemi yoo to foju ba ile ẹjọ.

Ileeṣẹ BBC ko tii ni gbolohun pẹlu afurasi naa lati gbọ latẹnu rẹ nipa gbogbo ohun ti awọn ọlọpaa sọ.