Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá Eko gbàlejò Obìnrin tí wọ́n jí gbé tọmọ tọmọ tí BBC Yoruba gbé ìròyìn rẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn oṣiṣẹ rẹ kan ṣe bere owo lọwọ obinrin to lọ fi ọrọ lọ wọn lẹyin ti wọn ji gbe.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun ni Naijiria, Muyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Igbeṣe yii lo n waye lẹyin ti ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba ṣe ifọrọwerọ fun obinrin ọhun, Rukayat Sodiq, lẹyin to moribọ lọwọ awọn ajinigbe niluu Eko.
Ni kete ti BBC gbe iroyin ohun to sẹle si obinrin naa jade, paapaa ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ọlọpaa ni iroyin ọhun fa ori ayelujara ya.
Ohun ti ọlọpaa sọ
Gẹgẹ bii ohun ti Adejobi sọ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbalejo obinrin naa lati ri si ẹsun to fi kan agọ ọlọpaa Igando.
O ni “Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko ti gbalejo obinrin ti wọn wu iwa ibajẹ si ni agọ ọlọpaa Igando lẹyin to gbe ẹjọ lọ sibẹ latari bi wọn ṣe ji gbe, eyii ti ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba gbe iroyin rẹ.”
“Inu wa yoo dun ti awọn araalu ba n fọ ilu mọ nipa kike sita ti awọn ọlọpaa ba ṣaṣiṣe si wọn.”
“Adupẹ lọwọ ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba fun akitiyan wọn... Mo tun dupẹ lọwọ kọmiṣọna ọlọpaa, Idowu Owohunwa fun akitiyan rẹ lati fo ilu mọ.”
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ
Jẹjẹ ni Rukayat n jade ni ọjọ kan ninu oṣu kini ọdun yii ni agbegbe Igando, ipinlẹ Eko, to si ṣe kongẹ agbako lọwọ awọn ajini-ji-ọmọ gbe.
Rukayat ṣalaye pe awọn kọlọrọsi naa ji oun gbe amọ lẹyinorẹyin, oun moribọ latari bi ọmọ oun ko ṣe dakẹ ẹkun.
Lẹyin iṣẹlẹ naa lo lọ fi ọrọ ọhun sun ni agọ ọlọpaa, ti awọn ọlọpaa si sọ fun pe awọn ko ni bẹrẹ iwadii ọrọ rẹ ayafi to ba kọkọ fun awọn ni owo.












