Kò si ohun tò ṣe "Bursar" Fáṣítì LASU, Akọwe owó ẹ̀ka ìmọ̀ òfin ló gbẹ̀mí mì-Aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Oṣiṣẹ faṣiti ipinlẹ Eko kan Johnson Adesola Ademola lo ti padanu ẹmi rẹ ninu ile ifowopamo kan to wa ninu ọgba fasiti naa.
Awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa ni Adesola wa lori ila lati gba iwe sowedowo ẹgberun marun owo naira tuntun lasiko ti ọlọjọ de ba a.
Awọn toro na soju wọn ni oloogbe Adesola ti ji de banki naa lati ago mẹfa owurọ.
Adesola ti ọpọ eeyan mo si Ọjọgbon dede subu lulẹ ninu banki ohun, gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi rẹ si lo jasi pabo, ki wọn to gbe oku rẹ lọ si yara igboku pamọ si ti ile iwe LASU fun ayẹwo.
Ta ni ologbe naa?
Adele alukoro ile eko Fasiti LASU Olaniyi Jeariogbe ṣalaye wi pe lodi si iroyin to wa loju awọn iwe iroyin kan pe Adesola jẹ igba keji alamojuto eto owo ile iwe LASU saaju ipapoda rẹ.
Olaniyi ni irọ to jina si ootọ ni nitori kokoko lara ọta alamojuto eto owo Fasiti LASU ọgbẹni Saheed Olayinka le.
O fi kun pe Oloogbe Adesola jẹ alabojuto isuna ẹka ẹkọ imọ ofin fasiti LASU, Adele alukoro fasiti LASU ni Oloogbe Adesola lọ si banki lati gba owo fun ara rẹ ni, Fasiti LASU kọ lo ran an ni isẹ.
Olaniyi ni ọdun 1986 ni Adesola ti bẹrẹ isẹ ni fasiti LASU gege bi atẹwe, o ṣapejuwe Oloogbe naa gẹgẹ bi akinkanju oṣiṣẹ ti oun wa ilọsiwaju ile iwe LASU.















