Ìpínlẹ̀ mẹ́wàá gbé Buhari lọ síwájú 'Supreme court' lẹ́ẹ̀kansi, láti wọ́gilé àṣẹ rẹ̀ lórí N1000 àti N500 tó gbẹ́sẹ̀lé

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency/other/kaduna governor/twitter
Awọn ijọba ipinlẹ mẹwaa kan lorilẹede yii tun ti gba ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lọ pe ki ile ẹjọ naa pa aṣẹ lati wọgile aṣẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari pa lati gbẹsẹle ninu owo beba olodindi ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta naira.
Ọjọ Ẹti ni agbẹjọro fun awọn ipinlẹ mẹwaa naa, A.J. Owonikoko, SAN pe ẹjọ ọhun ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, ‘Supreme Court’ pe ki ile ẹjọ ọhun paṣẹ pe ọrọ apilẹkọ ti aarẹ ka ni Ọjọbọ ati awọn aṣẹ to pa ninu rẹ ko ba ofin mu.
Awọn olupẹjọ ni awọn amofin agba ipinlẹ Kaduna, Kogi, Zamfara, Ondo, Ekiti, Katsina, Ogun, Cross river, Sokoto ati ipinlẹ Eko. Agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria, Abubakar Malami SAN atawọn akẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Bayelsa ati Edo ni olujẹjọ.
Wọn ni aṣẹ ti aarẹ pa lati fi kun iye akoko ti owo beba igba naira odindi yoo ṣi fi wulo jẹ “ aṣilo agbara ati titẹ aṣẹ ofin” ti ile ẹjọ to ga julọ naa ni pẹlu bi o ṣe jẹ pe ẹjọ ọhun ṣi wa niwaju ile ẹjọ ọhun.
Ni ibẹrẹ ọdun 2023 ni banki apapọ Naijiria, CBN gbe aṣẹ kalẹ pe nigba to ba fi di ọjọ kẹwaa oṣu keji wọn ko ni gba owo owo beba olodindi ẹgbẹrun kan (N1000), ẹẹdẹgbẹta (N500) ati igba naira (N200) mọ.
Aṣẹ naa n waye lẹyin ti gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn to kọkọ fi sita pari.
Amọṣa lẹyin ariwo, awuyewuye ati ọpọlọpọ wahala kaakiri orilẹede Naijiria nitori ọwọngogo naira naa, aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lọjọbọ nibi to ti sọ pe oun yoo tubọ sun okun ẹmi owo beba igba naira odindi siwaju fun ọgọta ọjọ di ọjọ kẹwaa oṣu kẹrin.

Amọṣa, oniruuru ariwisi lo ti n jade si igbesẹ naa lati ọdọ ọpọ ọmọ Naijiria titi kan awọn gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu.
Awọn gomina ipinlẹ bii Nasir El-Rufai (Kaduna), Abubakar Badaru (Jigawa), Rotimi Akeredolu (Ondo), Umar Ganduje (Kano); Olori ile igbimọ aṣofinṣoju, Fẹmi Gbajabiamila; Minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ, Festus Keyamo ati ọpọ awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn ti bọ si gbangba ode lati tako aṣẹ aarẹ yii ti wọn si ni arẹ ko laṣẹ lati sọ ọrọ naa nitori pe ẹjọ naa ṣi wa niwaju ile ẹjọ.
Bakan naa lawọn aṣiwaju amofin bii Fẹmi Falana SAN ati Mike Ozekhome SAN pẹlu tako aarẹ ti wọn si ni ko lẹtọ lati tako ọrọ ile ẹjọ ‘Supreme court’ to ga julọ lorilẹede Naijiria.












