Ìgbéjáde owó náírà tuntun ṣàfihàn àwọn kùdìẹ̀kudiẹ ààrẹ Buhari - El-Rufai

Oríṣun àwòrán, PRESIDENCY/NASIR EL-RUFAI
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai ní gbogbo ìfàǹfà tó ń wáyé lórí àyípadà owó náírà àti níná owó ti tẹ́lẹ̀ ti ṣàfihàn àwọn kùdìẹ̀kudiẹ ààrẹ Muhamaadu Buhari.
El-Rufai ní gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí fi àwọn àṣìṣe ààrẹ Muhammadu Buhari gẹ́gẹ́ bí olórí hàn ni.
Bákan náà ló tún tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ tó ti ṣáájú sọ wí pé àwọn kan wà ní ilé ààrẹ ní Aso Rock tí wọ́n ń ṣi ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́kàn lórí ọ̀rọ̀ owó tuntun yìí nítorí wọ́n fẹ́ kí APC fìdí rẹmi lásìkò ìbò.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí El-Rufai ṣe pẹ̀lú BBC, ó ní gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nípa owó kò ní dá olùdíje àwọn dúró láti gbégbá orókè lásìkò ìbò.
Gómìnà náà ní lẹ́yìn tí oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Tinubu bá di ààrẹ tán ni àwọn máa fi gbogbo àwọn aṣebi tó wà ní Aso Rock hàn sí gbangba.
Wọ́n mọ̀-ọ́n-mọ̀ gbé ètò pípáàrọ̀ owó kalẹ̀ ní ìbò ku ọjọ́ péréte láti tàbùkù ẹgbẹ́ wa ni – El-Rufai
Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni àwọn ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn láti tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè yìí lórí ọ̀rọ̀ owó náírà tuntun.
El-Rufai ṣàlàyé pé àwọn jíròrò lórí bí wọ́n ṣe gbé ètò ṣíṣe àyípadà owó náírà kalẹ̀ ní bí ó ṣe ku ọjọ́ díẹ̀ kí ìdìbò wáyé láti mú kí ẹgbẹ́ àwọn dàbí aláìda lójú àwọn ọmọ Nàìjíríà.
“Àwọn tí wọ́n gbé ètò yìí kalẹ̀ fẹ́ jẹ́ kí ẹgbẹ́ wa pàdánù ìbò ààrẹ ni”.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bóyá àwọn gómìnà náà ló wà nídìí bí alága ẹgbẹ́ wọn náà ṣe fẹnukò pẹ̀lú wọn lórí ọ̀rọ̀ náà, ó ní àwọn kò ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀.
“Kò sí ohun tó jọ mọ́ kíkó sí alága ẹgbẹ́ wa lórí láti gba tiwa, kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé ètò yìí kò dára tó nítorí ìnìra tó ń kóbá ará ìlú.”
“Kìí ṣe wí pé ètò ìdìbò gan ló jẹ wá lógún nítorí a mọ̀ wí pé àwọn ènìyàn máa dìbò fún wa nítorí àwọn iṣẹ́ tí ẹgbẹ́ wa ti ṣe.”
Kìí ṣe òní ni àwọn ènìyàn ti ń ra ìbò
Lórí ìròyìn pé nítorí à ti lè mú àdínkù bá ìbò rírà ni ààrẹ Buhari ṣe gbé ètò náà kalẹ̀, El-Rufai ní àwọn kìí ra ìbò ní Kaduna nítorí iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ni àwọn ènìyàn fi ń dìbò fún àwọn.
El-Rufai ní òun kò ṣe iyè méjì lórí pé bóyá Bola Tinubu àti gbogbo àwọn olùdíje àwọn yòókù máa wọlé ní Kaduna.
“Ṣé òní ni ìbò rírà bẹ̀rẹ̀ ni, àbí kí ló dé tí wọn kò ṣe pààrọ̀ owó láti ọjọ́ yìí tẹ́lẹ̀ àbí ṣe owó náírà nìkan ni ènìyàn fi le ra ìbò ni?”
“Ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò le fún àwọn ènìyàn ní owó ilẹ̀ òkèèrè, oúnjẹ tàbí àwọn nǹkan mìíràn àti pé ènìyàn kò lè yọ ọ̀rọ̀ owó kúrò nínú ètò ìdìbò.”
Ó fi kun pé gbogbo àwọn ariwo àti akitiyan tí àwọn ń pa kìí ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìbò bíkòṣe ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ń kojú lórí ìgbẹ́sẹ̀ náà.
Kí ló fa ìyapa abẹnu lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC?
Gómìnà El-Rufai ní gbogbo àwọn tó wà nídìí ìjà fún níná owó náírà tuntun kìí ṣe ojúlówó ọmọ ẹgbẹ́ àwọn bíkòṣe àwọn tó kàn fẹ́ kó ìfà lásán.
Ó ní ó hàn gbangba pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fi gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà, CBN, sípò àti pé gbogbo àwọn tí wọ́n jọ gbèrò rẹ̀ kìí ṣe ènìyàn àwọn.
“Àwọn ènìyàn yìí fẹ́ pa ẹgbẹ́ wa lára ni, àwọn tó jẹ́ wí pé nǹkan nira fún ní ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn àmọ́ tí wọ́n ti rí owó ńlá lásìkò yìí.”
“Gbogbo àwọn ènìyàn yìí ló máa ṣàlàyé bí wọ́n ṣe rí owó wọn nígbà tó bá yá.”
Ó ní ààrẹ Muhammadu Buhari jẹ́ ẹni tí kìí pẹ́ gbára lé ènìyàn nítorí náà ni wọ́n ṣe ń lò ó láti fẹ́ bá orúkọ àwọn jẹ́, tí wọ́n ń parọ́ fun pé olè ni àwọn gómìnà.
El-Rufai ní tí àwọn bá ṣèpàdé pẹ̀lú Ààrẹ Buhari, tí àwọn fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ kan, ní kété tí àwọn bá ti kúrò níbẹ̀ ni wọ́n ti máa sọ nǹkan mìíràn fun.
Ó ní lórí ọ̀rọ̀ owó náírà tuntun yìí, ààrẹ ṣe àṣìṣe tó pọ̀ gan.












