Ta ni Nuhu Ribadu tí Ààrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò olùbádámọ̀ràn lórí ètò àbò?

Nuhu Ribadu

Oríṣun àwòrán, Adamu Garba

Aarẹ Bola Tinubu ti yan Nuhu Ribadu gẹgẹ bii olubadamọran pataki nipa eto abo ni Naijiria.

Inu awọn ọmọ Naijiria kan dun si igbesẹ naa, bẹẹ lawọn mii n woye pe ta ni Ribadu gan, ati pe ki ni pataki ipo tuntun ti Aarẹ ṣẹṣẹ yan an si.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1960 ni wọn bi Nuhu Ribadu, ni ilu Yola, to jẹ olu ilu ipinlẹ Adamawa.

Awọn ibi to ti kawe

O lọ sile ẹkọ Aliyu Mustapha Primary School, niluu Yola lati ọdun 1966 si 1973, ati Yelwa Government Secondary School, Yola lati ọdun 1973 si 1977.

Lọdun 1980, o lọ kẹkọọ nipa imọ ofin laarin ọdun 1980 si 1983, lẹyin to pari eto agunbanirọ rẹ lo darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa.

Ribadu tun kawe ni Harvard Business School to wa nilẹ Amẹrika .

Awọn aṣeyọri ati ami ẹyẹ

Oun ni alaga akọkọ fun ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanuni Naijiria, EFCC, nibi to ti gbogun ti awọn eeyan kan to n lu owo ni ponpo, ninu eyii ti ọpọ ninu wọn jẹ gbajumọ oloṣelu.

Ribadu gba oniruru ami ẹyẹ gẹgẹ bii ọlọpaa, oluwadii iwa ọdaran ati gẹgẹ bii alaga EFCC laarin ọdun 1997 si 2005.

Lọdun 2010, fasiti Babcock, nipinlẹ Ogun fun ni oye Ọmọwe nipa imọ ofin ‘honoris causa’ fun awọn iṣẹ ribiribi to ti ṣe.

Lati ọdun 2010 lo ti n fi ara rẹ jin fun eto oṣelu ni Naijiiria.

Ribadu wa pẹlu Aarẹ Bola Tinubu nigba to ṣabẹwo siluu Owo, nipinlẹ Ondo, lẹyin ti awọn agbesumọmi ṣekupa awọn olujọsin mẹtalelogoji ninu ile ijọsin kan nibẹ lọdun 2022.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii ni Aarẹ Tinubu kede rẹ fun ipo olubadamọran si ijọba Naijiria lori eto abo.