Òkú tó jí dìde lásìkò tí wọ́n fẹ́ sin-ín padà kú pátápátá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan

Oríṣun àwòrán, Others
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àìrìn jìnà láì rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, mẹ́wàá ń ṣẹlẹ̀ ní dúnníyàn.
Ohun tó fẹ́ fara jọ èèmọ̀ luputupẹ́bẹ́ rèé nígbà tí òkú tí wọ́n fẹ́ sin ṣe kan ilẹ̀kùn pósí wí pé òun kò kú o.
Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹfà ni àwọn dókítà ní ìyá kan, Bella Montoya ti jẹ́ Ọlọ́run ní pè lẹ́yìn àìsàn kan tó ń ba fínra.
Lẹ́yìn tí àwọn dókítà ní ìyá náà ti kú ni àwọn ẹbí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ètò láti sin òkú rẹ̀ tí wọ́n sì gbé sínú pósí fún ètò ìsìnkú.
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn wákàtí márùn-ún tí wọ́n ti kéde pé ìyá náà ti kú ni ó bá kan pósí náà pé òun kò ì tíì kú.
Èyí ló mú kí àwọn ẹbí rẹ̀ tún gbe dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú ṣáájú fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú mìíràn.
Iléeṣẹ́ ètò ìlera orílẹ̀ èdè náà ní àwón ti ń ṣe àyẹ̀wò Montoya, tí àwọn sì ń fún ní ìtọ́jú tó péye.
Àwọn onímọ̀ ìlera ní ààrùn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ catalepsy- èyí tó máa ń jẹ́ kí ènìyàn dákú lọ gbọranganda, tí yóò jẹ́ kó dàbí wí pé ẹni náà ti kú ló ń ṣe ìyá ọ̀hún.
Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí ìyá ọ̀hún jí dìde, tó sì ti ń gba ìtọ́jú, iléeṣẹ́ ètò ìlera ní ìyá náà ti kú pátápátá báyìí.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ iléeṣk náà ní àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ ló ṣekúpa ìyá náà.
Wọ́n ní fún gbogbo ìgbà tí ìyá náà fi ń gba ìtọ́jú yìí, àwọn ṣe àmójútó rẹ̀ gidigidi àti pé àwọn ti ṣe àkójọ àwọn onímọ̀ láti ṣàyẹ̀wò irú àìsàn tí ìyá náà ní.
Ọmọ ìyá ọ̀hún, Gilbert Barbera ní ìyá òun ti pàpà papòdà báyìí àti pé ìgbé ayé òun kò lè rí bákan náà mọ́ lẹ́yìn ikú ìyá òun.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí òkú yóò jí dìde lẹ́yìn tí àwọn dókítà bá ti kọ́kọ́ kéde wọn pé wọ́n ti kú.
Nínú oṣù Kejì ọdún yìí, wọ́n bá ìyá ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin kan tó ṣì ń mí ní ilé ìsìnkú ní New York, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ kéde rẹ̀ pé ó ti kú.














