'Lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń kọrin ìyìn kí wọ́n tó sùn ni àwọn agbéṣùmọ̀mí dáná sun wọ́n'

Àwọn ẹbí tó pàdánù ọmọ wọn lásìkò ìkọlù náà

Oríṣun àwòrán, AFP

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama Mmponde Lhubiriha tí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ìkọlù sí lọ́jọ́ Ẹtì ń kọrin ìsìn lọ́wọ́ ni kí ìkọlù náà tó wáyé.

Mary Masika, tó ń gbé ìdojúkọ ilé ẹ̀kọ́ náà sọ fún BBC pé orin ìyìn ni wọ́n ń kọ lọ́wọ́ kí òun tó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ariwo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Níbi ìkọlù ọ̀hún tí wọ́n ní àwọn ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn Islam, “Allied Democratic Forces” ló ṣe agbátẹrù rẹ̀ ni ẹ̀mí ènìyàn tó ní ogójì ti nù.

Àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ní ohun tí àwọn ń jà fún ni bí Ààrẹ Uganda, Yoweri Museveni ṣe ń fìyà jẹ àwọn mùsùlùmí ní orílẹ̀èdè náà.

Ní orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ni àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ti ń ṣọṣẹ́ wọ inú Uganda.

Mary Masika tó ń gbé níwájú ilé ẹ̀kọ́ náà
Àkọlé àwòrán, Mary Masika tó ń gbé níwájú ilé ẹ̀kọ́ náà.

Masika ní ìkọlù náà tó wáyé fún bíi wákàtí kan àbọ́ ti dá ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn òun àti àwọn olùgbé agbègbè ọ̀hún.

“Láti ìgbà tí ìkọlù náà ti wáyẹ ni mi ò ti rí oorun sùn mọ́.”

Ó ṣàlàyé pé ìṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni láti máa kọ orin tí wọ́n bá fẹ́ sùn lálẹ́, tí òun sì rò wí pé wọ́n ń ṣe eréepá ni nígbà tí òun gbọ́ ariwo kan lásìkò tí wọ́n ń kọ orin náà.

“À ṣé nǹkan tó burú jáì ló ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ náà tó tó ọgọ́ta nínú ilé ìgbé wọn.”

Masika ní àwọn agbéṣùmọ̀mí náà wọ inú yàrá tí àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ náà ń sùn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dáná sun wọ́n, tí wọ́n sì tún ń fi àdá ṣá wọn pa.

Ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n dáná sun
Àkọlé àwòrán, Ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n dáná sun

Ẹbí kan ní Mpondwe ṣe ìsìnkú bàbá àti ọmọ tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù náà.

Bàbá, ẹni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́ta ló jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò àti ọmọ rẹ̀ Masereka Elton, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù ọ̀hún.

Ọmọ wọn mìíràn, Brian Muhindo, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dógún tí òun náà ń lọ sílé ẹ̀kọ́ náà ti di àwátì báyìí, wọn ò mọ̀ bóyá ó wà lára àwọn mẹ́fà tí wọ́n jígbé lọ àbí ó wà lára àwọn tí wọn dáná sun mọ́lé.

Hurubana Kimadi Onesmus sọ fún BBC pé kò yé òun bí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ṣe rí ààyè wọ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún nítorí ètò ààbò tó wà níbẹ̀ gbópọn gidi.

Ó ní àwọn ọmọ ogun pọ̀ tó ń ṣọ́ agbègbè náà.

Ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n dáná sun

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà báyìí tí wọ́n sì fún àwọn òṣìṣẹ́ wa ní àkókò péréte láti fi ya àwòrán àwọn ilé tí wọ́n dáná sun náà.

Níṣe ni àwọn òṣìṣẹ́ wa ṣì rí ẹ̀jẹ̀ tó ti gbẹ nílẹ̀ níwájú yàrá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin tí yàrá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọkùnrin ṣì wà ní títì pa.

Ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn ọkpunrin náà kọ̀ láti ṣí ilẹ̀kùn fún àwọn agbéṣùmọ̀mí náà tàbí kó jẹ́ wí pé wọ́n tì wọ́n mọ́ inú ilé náà tí wọ́n sì dáná sun wọ́n ma ibẹ̀.

Masika fi kun pé lásìkò tí ìkọlù náà ti ń wá sópin, òun gbọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn agbéṣùmọ̀mí ọ̀hún ń bèèrè lọ́wọ́ ìkejì rẹ̀ pé ṣe iṣẹ́ náà ti parí tí wọ́n sì pariwo “Allahu Akbar” èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ló tóbi jùlọ.”

Ó ní lẹ́yìn náà ni ọ̀kan nínú wọn sọ pé àwọn ti da orílẹ̀ èdè Museveni rú.

Nígbà tó sọ̀rọ̀, Ààrẹ Museveni sọ wí pé òun ti ran àwọn ọmọ ogun sí orí òkè Rwenzori èyí tó wà ní ààlà Uganda àti DR Congo tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti rí òpin àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.

Àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́, pa ènìyàn 40, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ

Aworan

Kò dín ní àwọn ènìyàn ogójì tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí àwọn agbéṣùmọ̀mí lọ ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ kan ní Uganda.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló fara kásá ìṣẹ̀lẹ̀ jùlọ bí ó 'se lé ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ẹ̀mí wọn bọ́ sí ìkọlù yìí.

Bákan náà ni àwọn mẹ́jọ mìíràn tún farapa nínú ìkọlù ọ̀hún èyí tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ girama Lhubiriha ní Mpondwe.

Ìròyìn ní àwọn agbéṣùmọ̀mí náà jẹ́ èyí tí wọ́n rò wí pé wọ́n ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn alákatakítí ẹ̀sìn ní Uganda.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọjọ́ Ẹtì ni àwọn agbéṣùmọ̀mí Allied Democratic Forces (ADF) tó jẹ́ ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Uganda àmọ́ tó fi orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ṣe ibùjókòó ṣe ìkọlù yìí.

Ọlọ́pàá ní àwọn ọmọ ogun ti ń àwọn ikọ̀ náà tó gba páàkì Virunga sá lọ.

Wọ́n ní òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni àwọn ti rí ní ilé ẹ̀kọ́ náà, tí àwọn sì ti gbé àwọn òkú ọ̀hún lọ sí ilé ìwòsàn Bwera.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Uganda, Fred Enanga nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Kẹfà ní àwọn agbéṣùmọ̀mí náà jó ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níná tí wọ́n sì tún jí gbogbo àwón oúnjẹ wọn kó lọ.

Ó ṣeéṣe kí àwọn tó bá ìkọlù náà tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì lọ tó ogójì nítorí àwọn ará ìlú náà fara kásá rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ṣeéṣe kí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà tún jígbé nítorí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló ti di àwátì tí wọn kò mọ́ bí wọ́n ṣe rìn báyìí.

Máàpù

Oríṣun àwòrán, Others

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun, Felix Kulayigye nínú àtẹ̀jáde lórí Twitter ní àwọn ọmọ ogun tí ń gbìyànjú láti gba àwọn ènìyàn tí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà jí gbé sílẹ̀.

Iléeṣẹ́ ológun orílẹ́ èdè Uganda àti DR Congo ti jọ ní àjọṣepọ̀ ní ẹkùn ìlà oòrùn Congo láti fòpin sí ìkọlù àwọn ADF.

Ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ni àkọ́kọ́ ṣíṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ ní Uganda láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Nínú o’sù Kẹfà ọdún 1998 ni wọ́n jó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọgọ́rin níná mọ́ inú yàrá wọn ní ilé ẹ̀kọ́ Kichwamba Technical Institute.

Lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ológun tẹ̀ wọ́n rì ní ọdún 2001 ni wọ́n kó lọ sí ẹkùn àríwá Kivu ní DR Congo.

Ní ọdún 2015 ni ọwọ́ té ẹni tó dá ikọ̀ náà sílẹ̀, Jamil Makulu ní orílẹ̀ èdè Tanzania, tó sì wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Uganda báyìí.

Láti bí ogún ọdún ni ni ADF ti ń ṣọṣẹ́ láti DR Congo.