Àwọn ọmọ Naijiria fún Ààrẹ Bola Tinubu lórúkọ tuntun nítorí àwọn ìgbésẹ̀ tó ń gbé

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, bola tinubu

Awọn ọmọ Naijiria ka ti fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni orukọ tuntun kan ti wọn pe ni “Baba go fast.”

Itunmọ orukọ naa ni pe Tinubu ja fafa lẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bii Aarẹ.

Eredi orukọ tuntun ọhun ko ṣẹyin awọn igbesẹ atawọn aṣeyọri to ti ṣe lẹnu ọjọ diẹ to gori alefa.

Ti ẹ ko ba gbabe, orukọ ti awọn ọmọ Naijiria pe Aarẹ ana, Muhammadu Buhari ni “Baba go slow” iyẹn lẹyin ti ko ja fafa lati ṣe awọn nnkan ti awọn araalu n reti ko ṣe gẹgẹ bii Aarẹ.

Nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni Tinubu yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro, to si tun paṣẹ fun CBN lati ṣe awọn atunṣe si iye ti wọn n paarọ owo naira si dollar, iyẹn lẹyin to ti kọkọ jawe lọ rọọkun nilu fun gomina banki naa, Godwin Emefiele.

Ileeṣẹ iroyin Reuters sọ ninu atẹjade kan pe awọn igbeṣe Tinubu yoo gbe ọrọ aje Naijiria de ibi ti awọn oniṣowo agbaye ni afojusun pe yo de.

Reuters ni “lara awọn igbeṣe akin ti Aarẹ Bola Tinubu gbe ni gbedeke owo naira to yọ ati bo ṣe fopin si owo iranwọ epo bẹntiro, eyii to mu ki wọn maa ta epo bẹntiro ni ilọpo mẹta.”

“Awọn igbesẹ wọnyii yoo jẹ ki eto ọrọ aje orilẹ-ede naa gberu si.”

Ẹwẹ, awọn onimọ nipa eto ọrọ aje kan ti sọ pe yoo to akoko diẹ ki awọn to le fi igbagbọ wọn sinu awọn igbesẹ tuntun ti Tinubu n gbe boya yoo le so eso ree tabi bẹẹ kọ.

Amọ wọn fẹnuko pe ohun iwuri lawọn nnkann to ti gbesẹ lẹnu ọsẹ melokan to gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bii Aarẹ.

Ẹ̀yin Mùsùlùmí, ẹ forí jìn mí lórí ọ̀rọ̀ kan tí mo sọ, àṣìgbọ́ ni - Shettima

Igbakeji aare Naijiria, Kashim Shettima

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Kashim Shettima ti ní kí àwọn Mùsùlùmí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà forí jin òun lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí òun sọ nígbà tí wọ́n fẹ́ yan àwọn adarí ilé aṣòfin.

Shettima ní ohun tí òun ń sọ kò yé àwọn ènìyàn pẹ̀lú ọ̀nà tí wọ́n bá òun tú ọ̀rọ̀ náà sí.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn kan pàápàá lórí ayélujára ń bú ẹnu àtẹ́ lu Shettima fún ọ́rọ̀ tó sọ wí pé ó sàn kí ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tó wà láti gúúsù Nàìjíríà jẹ adarí ilé aṣòfin àgbà, ju kí Mùsùlùmí láti ẹkùn àríwá tún gba ipò náà lọ.

Àmọ́ Shettima ti wá jáde pé Mùsùlùmí tọkàntọkàn ni òun tí òun sì ti ń ṣe ẹ̀sìn náà láti kékeré.

Ó ní òun kò gbèrò láti tàbùkù ẹ̀sìn Islam tó jẹ́ wí pé ẹ̀sìn tí wọ́n bí òun sí nìyẹn.

"N kò lè mọ̀-ọ́n-mọ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀sìn Islam tí wọn bí mi sí"

Nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀, Shettima ní òun sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà nítorí ìfẹ́ tí òun ní sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti pé ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè yìí ló jẹ òun lógún.

Ó ní pẹ̀lú bí nǹkan ṣe ń lọ ní Nàìjíríà, àwọn adarí orílẹ̀ èdè yìí gbọ́dọ̀ dìde sí bí Nàìjíríà yóò ṣe dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan.

Ó fi kun pé òun kò lè mọ̀-ọ́n-mọ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀sìn tí òun fi ọwọ́ bà àrà mú.

"Ẹ forí jìn mí, ènìyàn ni mí, kò sí kí ènìyàn má ṣe àṣìṣe, mò ń tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí àti Ọlọ́run."