Àṣírí ọkùnrin tó ní òun yóò pa gbogbo ẹ̀yà Igbo torí ìkórira tó ní sí wọn, tú sọ́wọ́ Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @Princemoye1
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti ni ọwọ awọn ti tẹ arakunrin to kede pe lori Twitter pe oun ti ṣetan lati maa pa awọn ara ẹya Igbo.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti kede pe ọwọ palaba arakunrin Kehinde Adesogba Adekusibẹ, to jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn ti segi.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ṣọ ọrọ kubakugbe si awọn eniyan to si tako ofin to de lilo ẹrọ ayelujara lorilẹede Niajiria.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Karun un, ọdun 2023 ni Adekusibẹ kọ si oju opo Twitter rẹ pe oun korira awọn ẹya Igbo.
Adekusibẹ ni "Ẹ jẹ ka pa gbogbo awọn ẹya Igbo yii, ẹ jẹ ki a le wọn kuro ni ilẹ Yoruba patapata, mo korira wọn pẹlu ẹmi mi.’’
Ọkunrin naa wa ṣapejuwe awọn ẹya Igbo gẹgẹ bi awọn ti ko fẹran ipa ati wahala, ti oun ko si fẹran wọn rara.
Bakan naa lo kesi awọn eniyan lati korira wọn lai wẹyin.
Ni kia ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti bẹrẹ iwadii nipa rẹ, ti wọn si ri arakunrin naa gbamu nibi to sa pamọ si nilu Ilesa, ni ipinlẹ Osun.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fikun un pe arakunrin naa ti jẹwọ pe lootọ ni oun sọ ọrọ kubakugbe naa.
Nibayii, wọn ni awọn n gbe ọkunrin naa lọ si ileẹjọ lẹyin ti wọn ba pari iwadii wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa lo asiko yii lati kesi awọn araalu pe ki wọn jawọ ninu iwa ibajẹ nitori awọn ni gbogbo nnkan ni ikawọ awọn, lati koju iwa ibajẹ gbogbo ni awujọ.















