Fertility in Men: Ìwádìí fihàn pé ọ̀pọ̀ ọmọ tí arúgbó ọkùnrin bá bí ló máa ń jẹ́ Aràrá

Aworan

Awọn ami ma n fi ara wọn lati fihan pe awọn ọkunrin ti n dagba, nigba miran, ti yoo si fihan pe wọn ti n dogbo.

Amọ n jẹ ṣe nkan ọmọkunrin wọn naa ma n dagba abi kii gbo rara?

Laipẹ yii ni gbajugbaja osẹre fiimu, Al Pacino, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgọrin kede pe oun ati ọrẹbinrin oun, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun, Noor Alfajah ti loyun, ti awọn si n reti ọmọ.

Bakan naa ni akẹgbẹ rẹ, Robert De Niro to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgọrin, naa kede pe oun n reti ọmọ oun keje.

Awọn ọkunrin meji yii nikan kọ ni wọn ti bimọ ni ọjọ ogbo wọn, ti a si ti ri ọpọ oṣere, ọlọla ati gbajumọ to fi mọ aarẹ orilẹede Amẹrika, to ti bimọ nigba ti wọn ti dagba.

Bakan naa ni iye awọn agbalagba to n bimọ si ti n peleke si ni awọn ọdun diẹ sẹyin.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

''Guiness World Records'' ni ẹni ọdun mejilelaadọrun ni baba ọmọ to dagba julọ lagbaye

Laarin ọdun 1972 si 2015 ni iye awọn agbalagba to n bimọ si peleke pẹlu idamẹta aabo, ti awọn ọkunrin to n bimọ si jẹ ẹni ọgbọn ọdun si ogoji ọdun nigba ti wọn bi ọmọ akọkọ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ''Guiness World Records'', ẹni ọdun mejilelaadọrun lo jẹ ọkunrin to dagba julọ lagbaye nigba to di ọlọmọ.

Amọ iroyin ti ko fidimulẹ sọ wi pe awọn ọkunrin to dagba ju eyi wa laye ti wọn bimọ ni ọjọ ogbo wọn.

Amọ ki ọkunrin di ọlọmọ nigba ogbo rẹ ni ọpọ ewu...

Ni Oṣu Kejila, ọdun 2022, awọn onimọ lati fasiti Utah ati fasiti miran fi lede pe ọjọ ori ti eniyan ba bimọ nii se pẹlu ipo iloyun ati ilera awọn ọmọde.

Àkọlé fídíò, IVF: Ìyá ìbejì se IVF mẹ́ta lókè òkun, ìkẹrin tó se ní Nàíjíríà, ló fi bímọ

Ọjọ ori ọkunrin to ni oyun nii se pẹlu ati bimọ obinrin ati bi oyun se n bajẹ lara obinrin

Bi o tilẹ jepe, a ri awọn agbalagba ti wọn n di ọlọmọ, amọ iwadii fihan pe atọ ọmọkunrin ki n munadoko mọ to ba ti n dagba.

Ayipada to n deba ara fihan pe ọjọ ori nii se pẹlu ati bimọ obinrin ati bi oyun se n bajẹ lara obinrin gẹgẹ bi iwadii se fihan.

Iwadii tun fihan pe oyun bibajẹ lara obinrin nii se pẹlu ọjọ ori baba ọmọ naa.

Bakan naa ni o ṣeeṣe ki aisan bẹrẹ lara ọmọ naa lẹyin ibimọ.

Aworan

Ọpọ ọmọ tuntun ti arugbo ọkunrin ba bi lo saba maa n jẹ Aràrá

Iwadii lati bi ọdun 1950 fihan pe awọn ọmọ ti wọn ba bi nigba ti baba wọn dogbo ma n saba jẹ Aràbá, ti awọn oloyinbo n pe ni ''achondroplasia''.

Amọ lati igba naa ni awọn aisan wa to jẹ mọ asiko ti wọn n bimo.

''Iwadii ti fihan pe iye ọjọ ori baba ati iya nii se pẹlu iru ọmọ ti wọn bi ati ilera ọmọ naa.

Bakan naa ni wọn ni o seese ko nii se pẹlu bi ọmọ naa ṣe kere si.

Igba miran ẹwẹ, wọn ni o nii se pẹlu awọn iru aisan jẹjẹrẹ to n ba awọn eniyan finra to fi mọ aisan ọkan.

Amọ o dara ki awọn eniyan ni imọ pe ko si ẹni to le fi idi rẹ mulẹ pe awọn aisan yii nii se pẹlu ọjọ ori ti baba fun iya ọmọ ni oyun rẹ.

Àkọlé fídíò, Láti ìgbà tí mo ti n wọ àmì ìdánimọ̀ Naijiria ni mo ti n rí àmì rere

Ọjọ ori ọkunrin nii se pẹlu airọmọbi oun ati aya rẹ

Iwadii fihan pe nigba miran o nii se pẹlu igbe aye awọn obi, to fi mọ iru aisan to lee ṣe awọn ọmọde lẹyin ibimọ.

Itan fihan pe awọn obinrin ni wọn saba ma n fi oju si lara ti nkankan ba ṣe oyun lara obinrin.

Bi o tilẹ jẹ pe obinrin nii se pẹlu airọmọ bi, iwadii ti fihan pe ọjọ ori ọkunrin naa nii se pẹlu airọmọ bi.

Nitori naa, ti awọn iṣẹlẹ airọmọbi ba n peleke si abi ti awọn agbalagba n bimọ ni ọjọ ogbo wọn, awujọ ati ẹka eto ilera gbọdọ bẹrẹ si ni tun ero ati imọ wọn ro.