Ọmọ MKO Abiola gbé ìbéèrè kàǹkà kalẹ̀ nípa bàbá rẹ̀ fún Tinubu níbi àdúrà ọgbọ̀n ọdún June 12

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹnìkan lára àwọn ọmọ olóògbé Moshood Kashimawo Abiola, MKO, ti sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ìjọba Ààrẹ Bola Tinubu, láti ṣe ohun tó yẹ fún ìrántí bàbá àwọn.
Hammed Abiola, sọ ọ̀rọ̀ nàá lásìkò tó kópa níbi ètò àdúrà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ṣe agbátẹ̀rù rẹ̀ ní ilé mọ̀lẹ́bí Abiola nílùú Abeokuta.
Èyí n wáyé láti ṣe àmì ọgbọ̀n ọdún tí ìjọba ológun wọ́gilé èsì ìdìbò tó yẹ kó sọ MKO Abioa di ààrẹ Naijiria.

Ọgbẹni Hammed Abiola sọ pé ìgbàgbọ́ àwọn ni pé ìjọba tuntun tí ó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà báyìí lábẹ́ Ààrẹ Bọlá Tinubu yóò gbé òye GCFR tí ìjọba to lọ kùnà láti fi bu ọlá fún bàbá àwọn lẹ́yìn tí ó kú tán.
O ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba Mohammed Buhari tó kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù Kẹfà gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ ìṣèjọba àwaarawa ní Nàìjíríà dípò ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún tó n wáyé tẹ́lẹ̀ láti fi bu ọlá fún MKO.
"Ìgbàgbọ́ wa ni pé, Aare Tinubu yóò ṣe ju bẹ lọ nípa fífi òye GCFR àti ẹtọ tí ó yẹ kí bàbá wa gba gẹgẹ bii ẹni tí ó borí ibo June 12, 1993, ní Nàìjíríà.

Kí ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ June 12?
Olóyè Moshood Kasimawo Abiola ni igbagbo wa pé ó jawe olubori nínú ètò idibo sípò Ààrẹ Nàìjíríà lodun 1993 lábẹ́ ẹgbẹ́ oselu SDP ṣùgbọ́n tí ìjọba ológun ìgbà náà, lábẹ́ Ibrahim Gbadamosi Babangida dá esi idibo náà nù.
Lẹ́yìn nàá ni ìjọba ológun Sani Abacha jùú sí ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn ìdìtẹ́ mọ́ ìjọba nípa àwọn ọ̀ǹa tó n gbà bèèrè fún 'ẹ̀tọ́ rẹ̀'.
Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Abiola kú sí ní ọjọ́ ọjọ́ keje, oṣù Keje, ọdun 1998 ní ẹni ọgọ́ta ọdún.















