Wo kókó ohun mẹ́tàlá tí Bola Tinubu ṣe bií Ààrẹ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló gbà pé àsìkò tí Bola Ahmed Tinubu gba ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà jẹ́ àsìkò tí nǹkan kò rọgbọ fún orílẹ̀ èdè yìí rárá.
Ọ̀pọ̀ ló ń ké ìrora pàápàá lórí ètò ọrọ̀ ajé, ètò ààbò àti àwọn ohun amáyédẹrùn mìíràn.
Ó jọ wí pé gbogbo àwọn nǹkan yìí ni Tinubu náà mọ̀ nípa èyí tí ọ̀pọ̀ rò wí pé ó fa àwọn ìgbésẹ̀ tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé lẹ́nu ìgbà péréte tí wọ́n búra wọlé fún un gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé ẹrù àgbà, ipò olórí kìí ṣe ohun kékeré rárá, àwọn nǹkan tí Tinubu kọ́kọ́ kojú ní ọ́fíìsì kò kéré rárá pàápàá lórí ọ̀rọ̀ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù.
Èyí ló mú wa ṣe àkójọ àwọn nǹkan mọ́kànlá tí Tinubu tí ṣe lẹ́nu ìgbà tó gba ipò Ààrẹ Nàìjíríà.
Tinubu yọ owo iranwọ lori epo pẹtiroolu
Ni ọjọ ti wọn n bura fun aarẹ Bola Tinubu lọjọ Aje, ọjọ Kkanlelọgbọn osu Karun ọdun 2023 lo se ikede pataki kan.
Lasiko to n ka ọrọ akọsọ rẹ sawọn ọmọ Naijiria ni aarẹ Tinubu kede pe ‘Owo iranwọ epo Pẹtiroolu ti lọ’
Ni kete to si sọrọ yi tan ni awuyewuye gbalẹ kan, tawọn ile epo yika Naijiria si gbe ilẹkun wọn ti pa.
Lati igba naa si ni lita epo pẹtiroolu kan ti fo fẹrẹ si ẹẹdẹgbẹta Naira nigba to le aadọta Naira lawọn agbegbe miran.
Ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò

Oríṣun àwòrán, Twitter
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wí pé ètò ààbò ṣe pàtàkì fún ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè, ṣíṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ olùdámọ̀ràn àgbà lórí ètò ààbò wà lára àwọn nǹkan tí Ààrẹ kọ́kọ́ gbé ṣe.
Níbi ìpàdé náà, Tinubu tẹmpẹlẹmọ pé ó pọn dandan fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà láti ṣiṣẹ́ papọ̀ lójúnà àti wá ojútùú sí ìṣòro àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Tinubu ní ètò ààbò gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin tí ètò ọrọ̀ ajé yóò bá padà bọ̀ sípò ní Nàìjíríà.
Ṣe ìpàdé pẹ̀lú gbogbo àwọn gómìnà ìpínlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter
Níbi ìpàdé yìí ni Tinubu ti là á mọ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì yìí pé wọ́n nílò láti pa òṣèlú tì sí ẹ̀gbẹ́ kan ná, gbogbo wọn ní láti fọwọ́sowọ́pọ̀ kí wọ́n le mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.
Tinubu ní gbogbo àwọn gómìnà yìí àti ìjọba àpapọ̀ gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ àti pé èyí ló le mú ètò ìjọba àwaarawa dùn ún ṣe.
Yan Gbajabiamila gẹ́gẹ́ bí olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba
Ìgbésẹ̀ mìíràn tí Ààrẹ Tinubu gbé tó fà kí àwọn kan sáárá sí i ni bí ó ṣe yàn Abẹnugan ilé aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila gẹ́gẹ́ bí olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba.
Bákan náà ló tún yan Ibrahim Hassan Hadejia gẹ́gẹ́ bí igbákejì Gbajabiamila.
Èyí tí ń fún àwọn ènìyàn ní àpẹẹrẹ irú àwọn ènìyàn tó ṣeéṣe kí ó wà nínú ìgbìmọ̀ aláṣẹ Tinubu.
Yan Akume gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọba
Bákan náà ni Ààrẹ yàn Sẹ́nétọ̀ George Akume gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọba àpapọ̀.
Ààrẹ ní òun ní ìgbàgbọ́ pé Akume máa sin orílẹ̀ èdè dáradára nínú ipò náà.
Bá àwọn alágbàtà epo bẹntiróòlù ṣe ìpàdé

Oríṣun àwòrán, FGN
Nítorí à ti lè kojú àwọn ìpèníjà tó ṣúyọ lẹ́yìn yíyọ ìrànwọ́ orí epo, ààrẹ Tinubu ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn alágbàtà epo bẹntiróòlù ńlá.
Ó rọ̀ wọ́n láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba kí wọ́n bá lè máa pèsè epo tí yóò tó lò fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Lẹ́yìn ìpàdé náà ni àwọn alágbàtà náà kéde èròńgbà wọn láti ra ọkọ̀ akérò ńlá tó tó àádọ́ta sí ọgọ́rùn-ún láti mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn mẹ̀kúnnù ń kojú lásìkò yìí.
Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ Exxon Mobil láti túnbọ̀ lékún àjọṣepọ̀ wọn lẹ́ka epo rọ̀bì.
Pàṣẹ fún ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ọrọ̀ ajé láti pèsè ohun ìdẹkùn fara ìlú

Oríṣun àwòrán, Twitter
Lẹ́yìn tí ó ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alágbàtà epo, ààrẹ darí ìgbìmọ̀ ètò ọrọ̀ ajé lábẹ́ ìdarí Kashim Shettima láti tètè bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí wọ́n yóò fi wà àwọn ohun ìdẹ̀rùn fún ọmọ Nàìjíríà lórí ìrànwọ́ epo.
Ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́balọ́ba

Oríṣun àwòrán, Twitter
Lẹ́nu ìwọ̀nba ìgbà péréte tí Ààrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ lò lórí ipò, ó ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́balọ́ba, tó sì rọ̀ wọ́n láti ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba òun kí ìṣọ̀kan lè jọba ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Bákan náà ni òun náà sọ àrídájú àtìlẹyìn rẹ̀ láti kún àwọn ọba náà lọ́wọ́ lórí ojúṣe wọn.
Gba àṣẹ láti yan olùbádámọ̀ràn ogún
Nínú akitiyan rẹ̀ láti yan àwọn tó dáńtọ́ sípò ìjọba, Tinubu kọ̀wé sí ilé aṣòfin àgbà láti buwọ́lu ìyànsípò àwọn olùbádámọ̀ràn ogún.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi orúkọ àwọn wọ̀nyí léde, ilé aṣòfin buwọ́lu ìbéèrè náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wí pé yóò ran Ààrẹ lọ́wọ́ láti tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.
Ìjíròrò pẹ̀lú JOHESU
Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera JOHESU fi ń yan iṣẹ́ lódì ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣẹ́wẹ́lé ìyanṣẹ́lódì náà lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ.
Igbákejì Ààrẹ JOHESU, Obinna Ogbonna sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ìjíròrò tí àwọn ṣe pẹ̀lú Ààrẹ ló jẹ́ kí àwọn fòpin sí ìyanṣẹ́lódì náà.
Ó ní ọjọ́ mọ́kànlélógún ni àwọn fún ìjọba láti dáhùn sí àwọn ìbéèrè àwọn.
Fẹnukò pẹ̀lú NLC
Tinubu fẹnukò pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC láti má lọ fún ìyanṣẹ́lódì èyí tí wọ́n ń gbèrò lẹ́yìn tí ìjọba yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù.
Àwọn aláṣẹ ní ohun méje ni wọ́n fẹnukò lé lórí láti gbégi dínà ìyanṣẹ́lódì ọ̀hún.
Yọ Emefiele gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Collage
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kẹfà ni Ààrẹ Tinubu ní kí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele lọ rọ́kún nílé.
Ìgbésẹ̀ yìí ni iléeṣẹ́ Ààrẹ ní ó wáyé láti fi ààyè gba ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lórí Emefiele.
Tinubu bawọn ọmọ Naijiria sọrọ lati sami ayajọ June 12
Ni ọjọ ti a n sami ijọba alagbada JUne 12, aarẹ Bola Tinubu tun bawọn ọmọ Naijiria sọrọ lati le jẹ ki wọn mọ pataki ọjọ naa.
Tinubu, ẹni ti oun naa wa lara ikọ to jijagudu fun idapada ijọba alagbada lẹyinti ologun gbajọba lọdun 1993, wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ni iforiti siwaju diẹ si.
O sọrọ nipa bo se yọ owo iranwọ epo rọbi ati ọna ti eto idẹrun yoo gba de ọdọ awọn araalu.















