Ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tó bá ṣe ohunkóhun pẹ̀lú òkú mi yóò dara pọ̀ mọ́ mí lájùlé ọ̀run - Olubara

Olubara

Oríṣun àwòrán, Litcaf

Ọba Olubara ti ilu Ibara to wa ni Abeokuta, ipinlẹ Ogun, Alayeluwa Ọba Jacob Olufemi Omolade ti sọrọ nipa bo ṣe n lo igba aye re lori itẹ to si ti ni ati oku ati aye oun, oun ko fẹ ni nnkankan ṣe pẹlu ẹsin abalaye.

Oba Olatunji n so eyi lori eto opin ọsẹ ti iwe iroyin Punch.

Ṣé ẹ ṣẹ mọ pe ẹni ba maa jẹ Ọba gbudọ ṣe aṣa ibilẹ ni?

Ni kete ti wọn ṣe ayeye dide ade fun mi, awọn oloye pe mi won si ni idaji ọna ni mo ṣi de pẹlu awọn aṣa ibilẹ ati pe ohun to ku ni pe ki wọn mu mi wọn ẹgbẹ okunkun, ṣugbọn mo sọ pe rara tori pe baba mi gan, ẹlẹsin Kristẹni ni mo si fẹ tọ ipasẹ rẹ nitori pe o ni anfani tirẹ lati jẹ ẹni to n sin Ọlọrun kii ṣe ni ti ẹsin Kristẹni nikan.

“Koda too ba jẹ ẹlẹsin Musulumi, waa bọwọ fun Ọlọrun. Ọlọrun kan naa la n sọrọ rẹ. Ta lo mọ ẹni ti yoo lọ sọrun? Ti awọn araalu lo yẹ ka maa ro.”

O ni tori naa, nigba ti wọn sọ fun oun pe ko wọ ẹgbẹ awo, oun kọ “nigba ti wahala si fẹ pọ ju, mo fẹ kọ ilana naa silẹ, mo ko ẹru mi mo si sọ fun iyawo mi pe a n pada lọ si Eko tori pe mi o le sin oriṣa.”

Ọba Omolade ṣalaye pe wọn gbiyanju lati mu baba oun naa wọ inu ẹgbẹ awo nigba to jẹ Ọba ṣugbọn o kọ.

Ṣe awọn awo ko wa ki yin nilọ?

Olubara

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Wọn sọ fun mi loju koro koro wipe mi o ni lo to ọdun meji lori itẹ, ṣugbọn mo pa wọn ti. Mo bẹrẹ si ni gbadura ati awẹ bẹẹ si ni Alufa ijọ mi wa si ile mi ti a jọ ṣinu awẹ”.

O ni awọn bori pẹlu adura bẹẹ si ni awọn alawo ọhun fi oun lọrun silẹ.

“Igbesẹ wọn ko dẹru ba mi tori mo mọ wipe bi ile aye ṣe ri niyẹn, ninu ko la odo kọja tabi koo ba omi lọ, ọkan ni waa mu”.

Ọba Omolade ni oun ja oun si bori toripe Ọlọrun wa pẹlu oun titi di oni.

Ki lo maa n ṣẹlẹ bi Ọba ba waja?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọba Olamide ṣalaye pe laye atijọ, bi Ọba ba waja, wọn maa n ge ọwọ ati ẹsẹ rẹ ni.

“Awọn yoo mu ọkan lara ẹsẹ wọn yoo si sin in si oju ọna to lọ si ilu naa wọn a sin ẹsẹ keji si ọna ibomiran to ba wọ ilu ọhun ati pe o ṣeeṣe ki wọn si ori rẹ si Aafin”.

Amọ o ni ijọba lo dawọ aṣa yii duro ti wọn si ni aye ti laju ki a bẹrẹ si ni jẹ ki wọn sinku awọn Ọba wa ni ilana ẹsin ti wọn ba yan laayo.

“Bẹẹ ba wo bi wọn ṣe sin Alaafin Oyo, o ya mi lẹnu, wọn gbe e jade, awọn Musulumi kirun sii lara wọn si gbe e lọ si ibi itẹ lati sin in. Wọn o ba ma gba iru eyi laye laye atijọ ati pe bayii, igba ti yi pada ṣugbọn a ṣi ni awọn alawo laarin wa o”.

“Mo ti sọ fun lara awọn oloye mi mo si ti kilọ fun wọn wipe ẹnikẹni to ba ge ara mi nigba ti mo ba lọ tan tabi ẹni to ba dan idankudan wo yoo tẹle mi lọ ọrun ni”.

O ni: “Bi mo ba papoda, mo fẹ ki wọn gbe mi lọ si ibi itẹ to wa fun gbogbo eeyan, mo ti ra aye mi sibẹ, wọn ti gbẹ ilẹ naa, ti iyawo mi ko jina si temi nitori naa mo ti gbẹ ilẹ ti tọdọ mi awọn kan si ti ri i”.

Kabiyesi ni oun ti sọ fun wọn pe ki wọn gbe oun lọ si Ṣọọṣi fun adura.

“Mo ti kilọ fun gbogbo wọn ṣaaju pe ẹni to ba ṣe nnkan ibilẹ yoo tẹle mi, mo si n sọ eyi daju daju.

Bi adura mi yoo ba jẹ itẹwọgba tabi ko ni jẹ kii ṣe ẹjọ ẹnikẹni tori bi mo ba ṣe rere laye, yoo dara fun mi”.

Ọba Omolade wipe ofin to ni ṣe pẹlu ṣiṣe isinku awọn Ọba Alade ti di eyi ti wọn gba wọle gẹgẹ bi ofin wọn si ti buwọ lu u. “Tori naa, mo ti bọ bayii!”.

O ṣalaye wipe oun ati Awujale ti ilẹ Ijebu atawọn Ọba meji mii lawọn rii pe ofin yii di ohun tori naa ko si ọrọ a n ge ẹya ara eeyan. O ni ohun to ṣe pataki ni ẹmi, ẹmi si ti pada sọdọ ẹni to ti wa. Tori ara yoo pada parun yoo si bajẹ ninu ilẹ ti wọn ba sin oku si.

Ki lode ti ẹ waju mọ ipo Ọba gan?

Oriade naa to ti pe aadorun odun ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn irọ̀ oun ti awọn jọ kawe lo ti re ibi agba n re amọ o dupẹ pe o ṣi wa laye.

“Awa meje la ku ninu ọgọta. Aarẹ tẹlẹri, Obasanjo si wa lara wọn”.

Nigba ti wọn bi Oba yii pe ki lawọn nnkan ti yoo ranti ju gẹgẹ bii Olubara ati igba ti won fi jẹ oye, Oba Omolade ni oun ko tilẹ fẹ jẹ Oba nitori oun ri iru iya ti awọn to jẹ Oba ṣaaju oun jẹ ti oun si ro o wipe ko yẹ ki oun naa tun wa jẹ iru iya ọhun “ṣugbon awọn olori ẹbi wa ti mo ti bẹ pe ki wọn ma mẹnu ba ọrọ naa ti wọn si ti gba naa lo tun pada wa n bẹ mi lẹyin ọsẹ meji pe ki n gbe e yẹwo ki n si gba ade pẹlu atilẹyin awọn”.

“Koda nigba to jẹ pe awa mẹta ni a n du ipo naa, mo gbadura pe ki ọkan lara awọn meji to ku di Oba Ibara amọ ko seese fun wọn tori pe ọkan lara wọn kii ṣe mọlebi wa ati pe ekeji to jẹ mọlebi gan ko tilẹ le sọ itan idile wa”.

Ọdun 1992 ni Oba Omolade gba to si di Onibara ti Ibara titi di akoko yii.