Ìjọba ìpínlẹ̀ Edo dín lílọ sílé ìwé kù sí ọjọ́ mẹ́ta láàrín ọ̀sẹ̀

Oríṣun àwòrán, others
Ijọba ipinlẹ Edo ti kede pe ọjọ mẹta pere lawon akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ọdun mẹta akọkọ girama yoo maa fi lọ si ile ẹkọ lọsẹ bayii.
Igbesẹ tuntun yii, ti yoo rọpo ọjọ marun un ti wọn n lo tẹlẹ ni ijọba ipinlẹ Edo sọ pe yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, ọdun 2023 yii.
Alaga ajọ eto ẹkọ tẹrutọmọ, SUBEB, ni ipinlẹ ọhun, Ozavize Salamo lo sọ eyi fun awọn akọroyin nilu Benin lẹyin ipade pẹlu olori awọn oṣiṣẹ ijọba at’awọn eekan miran lẹnu iṣẹ ijọba nipinlẹ Edo.
Salami sọ pe “ọjọ Aje, Iṣẹgun ati Ọjọru nikan ni wọn ya sọtọ fun ile ẹkọ lilọ bayii nigba ti ile ẹkọ gbogbo yoo wa ni titipa ni Ọjọbọ ati ọjọ Ẹti.”
O ni erongba ijọba ni lati lo awọn ọjọ meji naa fi gbajumọ eto ẹkọ ori ayelujara lati lee ri pe gbogbo awọn ilana ẹkọ gbogbo to yẹ ni wọn kọ.
“A ti fi kun iye wakati t’awọn akẹkọọ yoo ma lo ni ile ẹkọ”
Bakan naa ni alaga ajọ SUBEB ni ipinlẹ Edo naa tun ṣalaye siwaju sii pe afikun yoo de ba iye wakati ti awọn akẹkọọ yoo maa lo ni ile ẹko.
Afikun naa yoo si kan awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ at’awọn ti ọlọdun mẹta akọkọ girama.
“A ti fi kun iye wakati ikẹkọọ ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ pẹlu wakati kan, nigba ti wakati meji yoo kun iye akoko ẹkọ ni awọn ile ẹkọ ọlọdun mẹta akọkọ ni girama.”
“Eyi yoo jẹ ki a le kọ gbogbo awọn koko ẹkọ to yẹ ki wọn kọ lọjọbọ ati ọjọ Ẹti.”
Bakan naa ni olori awọn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ naa, Anthony Okungbowa pẹlu ṣalaye pe adinku to ba iye ọjọ ti awọn oṣiṣẹ n lo lẹnu iṣẹ ko le e mu ifasẹyin ba ijafafa iṣẹ nibẹ.
O ni ijọba yoo pese awọn ọkọ akero bọọsi lati ile ijọba sẹkitariati ijọba at’awọn agbegbe miran lati din wahala awọn oṣiṣẹ ku.
O ni ijọba ti ṣofintoto awọn agbegbe mẹjọ kan ti awọn bọọsi akero yoo wa fun kiko araalu lati tubọ mu inira yiyọ owo iranwọ kuro lara epo bentiro.












