Ẹ̀ wó bí Àgbábọ́ọ́lù Naijiria, Táíwò Awóníyì ṣe gbé ògo ìdílé rẹ̀ ga lásìkò ìbẹ̀wò rẹ̀ sí Ilorin

Agbabọọlu fun orile ede Naijiria, Taiwo Awoniyi, baba ati iya re, pelu awon ọmọ iya rẹ kan s'ẹkun latari bi awon eniyan se n pokiki rẹ loni
Isele yii waye lori papa isere Sheik Abdulquadir College ni Ilorin, Olu Ilu Ipinle Kwara ni ibi idije bọọlu alafesegba, ti Taiwo Awoniyi je onigbọwọ rẹ.
Agbabọlu Taiwo Awoniyi lo se eleyii lati se awari ogo irawọ tuntun laarin awon ọdọ ni ipinle ti o dagba si.




Ni ipari idije naa, ti Taiwo Awoniyi n gba awon ọdọ ni iyanju ni awon eniyan n pariwo orukọ rẹ, ori re wu, osi bu si ẹkun, awon baba, iya ati awon ọmọ iya rẹ naa si pelu rẹ ninu si sun ekun ayọ naa.
Obẹrẹ si n kọrin lati dupẹ lọwọ ọlọrun, osi tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn to ran an lọwọ lati goke
Adari Ajo ton risi bọọlu alafesegba ni Kwara, Ọgbeni Idris Musa dupẹ lọwọ Taiwo pe oje ọmọ ti o ran ti ile
O gbadura pe ki o se aseyori ninu gbogbo idawọ le rẹ.








