Wo àwọn Gómìnà CBN tó jẹ ṣáájú Emefiele àti bí wọ́n ṣe parí sáà wọn

Banki apapọ Naijiria ni banki agba to n dari ọrọ eto iṣakoso ati nina owo lorilẹ-ede naa.
Lati igba ti wọn ti da banki naa silẹ ọpọ ọrọ eto inawo ọrọ aje ati iṣuna lo ni ṣe pẹlu iṣẹ banki apapọ yi.
Bi ọrọ aje orileede ba gunrege ninu awọn ti a le tọka si pe wọn kopa ninu rẹ ni banki apapọ.
Bi o ba si ku diẹ kaato naa, awọn eeyan a maa naka abuku si adari banki yii ati awọn ilana to ba gbe kalẹ lasiko rẹ lori oye.
Ko jẹ iroyin tuntun mọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti ni ki Gomina bani apapọ Naijiria Godwin Emefiele lo rọọkun nile tohun ti bi Aarẹ ṣe ni iwadii yoo tẹsiwaju lori awọn eto ati ilana ọrọ aje to gbe ṣe lasiko rẹ.
Njẹ Emefiele ni akọkọ Gomina banki CBN ti iru nkan bayii yoo ṣẹlẹ si?
Ẹ jẹ ki a ṣe agbeyẹwo ohun to ṣẹlẹ si awọn to jẹ ipo yi sẹyin.
Clement Nyong Isong

Oríṣun àwòrán, Google
Clement Nyong Isong lo jẹ Gomina CBN lasiko ijọba Gowon.
Lasiko rẹ, nkan rọsọmu daada fun ọrọ aje Naijiria ti owo si niyi daada ni igba naa lọhun.
Oun ni Gomina banki apapọ keji ti yoo jẹ ọmọ Naijiria.
Ọdun 1967 si 1975 lo fi di ipo yi mu.
Ọdun 2000 lo jade laye.
Aworan rẹ lo wa lori ẹgbẹrun Naira ti o di nina loṣu Kẹwa ọdun 2005.

Oríṣun àwòrán, Google
Alhaji Mai Borno
Akọkọ ọmọ Naijiria ree ti yoo jẹ Gomina Banki apapọ Naijiria.
Mallam Aliyu Mai-Bornu di ipo yi mu laarin July 25 1963 titi di June 22 1967.
Ọmọ bibi ipinlẹ Adamawa nii ṣe.
O kawe gboye nipa imọ ọrọ aje ni fasiti Bristol to wa ni ilẹ Gẹẹsi.
O di ipo adari ati ọga agba ileeṣẹ Nigerian Tobacco Company mu lẹyin to fi ipo rẹ silẹ ni CBN,1967-1969.
Ọjọ kẹtalelogun oṣu Keji ọdun 1970 lo jade laye.
Aworan rẹ pẹlu ti Clement Nyong Isong lo wa lara owo ẹgbẹrun Naira taa n na lonii.
Wọn ko yọ kuro lẹnu iṣẹ.
O pari saa rẹẹ ni gẹgẹ bi ti Clement Nyong Isong .
Adamu Ciroma

Oríṣun àwòrán, BULAMA
Ọmọ orileede Naijiria kẹta ti yoo di ipo Gomina mu ni CBN ni Adamu Ciroma.
Nigba aye rẹ o jẹ ẹni to fi ipa rẹ lelẹ nidi gbogbo nkan to dawọ lori.
O ṣiṣẹ lẹka iroyin , ni ile iṣẹ banki,o jẹ alakoso bẹẹ lo tun jẹ oloṣelu to dantọ.
Ọdun meji lo lori ipo Gomina Banki apapọ laarin ọdun 1975-1977.
Ko pẹ lori oye naa to fi finu fẹdọ kọwe fipo silẹ lọ sidi oṣelu.
O jẹ ọkan gboogi ninu awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party laarin ọdun 1999 si 2003.
Koda o di ipo Minisita feto iṣuna labẹ ijọba Aarẹ Olusegun Obasanjo.
Iyawo Adamu Ciroma,Maryam Ciroma lo jẹ ipo alaga obinrin ẹgbẹ oṣelu taa n wi yi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sanusi Lamido Sanusi
Wọn ni ki Sanusi Lamido Sanusi lọ rọọkun nile labẹ ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan lori ẹsun ''inakuna ati iwa ti ko tọ''
Ikede yi jẹ eleyi to mu iriwisi ọtọọtọ wa ni Naijiria.
Lọdọ awọn araalu kan akikanju ni Lamido Sanusi jẹ nitori o pariwo sita pe ogun biliọnu dọla owo to wọle si apo ijoba ni owo epo rọbi ni o dawati.
NNPC ni Sanusi fi ẹsun na kan ni igba naa ṣugbọn wọn ni ọrọ ti ko fẹsẹ mulẹ ni.
Ọpọ lo bọwọ fun Sanusi nitori awọn iyipada to mu ba ẹka ifowopamọ ni Naijiria.
Ọlọpọlọ pipe ni Sanusi jẹ ti wọn si da lọla gẹgẹ bi Gomina banki apapọ to dantọ julọ nigba naa lọhun.
Ọdun 2009 ni wọn yan sipo ṣugbọn wọn yọ nipo lọdun 2014.
O gba ile ẹjọ lọ lori bi wọn ṣe yọ kuro ti ile ẹjọ si da lare pe ijọba ko lẹtọ lati yọ bi wọn ṣe yọ.
Ọpọ ni ko ni gbagbe ipa ti Sanusi ko lẹka ifowopamọ pẹlu awọn iyipada to fi lelẹ.
Lara rẹ ni bo ṣe mu Islamic Banking wa si oju agbami ti o si fi ijiya jẹ awọn ile ifowopamọ kan to lu owo araalu ni ponpo.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Charles Soludo
Charles Soludo
Ọdun 2004 ni Charles Soludo dori alefaa gẹgẹ bi Gomina Banki apapọ.
Oun lo bẹrẹ awọn atunto lẹka ifowopamọ Naijiria ti Lamido pada wa fẹsẹ rẹ rinlẹ.
O fi ipo Gomina Banki naa silẹ́ lọdun 2009 lati lọ dije ipo Gomina Anambra.












