Bí àwọn ọmọ mẹ́rin sẹ jàjàbọ́ nínú aginjù rèé lẹ́yìn tí ìyá wọn kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bàálù

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ni Ọjọ Ẹti ni ikọ ọmọogun ilẹ Columbia doola ẹmi awọn ọmọ mẹrin ti wọn ha sinu igbo aginju lorilẹede Columbia, ti gbogbo orilẹede si ti n gbadura fun awọn ọmọ naa lati ye.
Inu gbogbo araalu lo dun lẹyin ti ẹrọ redio dun ninu igbo aginju, ti wọn si fo fun ayo pe wọn ti ri awọn ọmọ naa.
Ariwo to gba agbegbe naa kan ni pe ‘’Miracle, miracle, miracle, miracle- ‘’iyanu, iyanu, iyanu, iyanu!’’
Ọrọ awọn ikọ ologun yii tun mọ pe awọn ọmọ ti wọn ti n wa fun ogoji ọjọ ni wọn ti ri laaye.

Awọn ọmọ naa ti wọn wa lati agbegbe Huitoto, ni wọn jẹ ọmọ ọdun mẹtala, mẹsan, mẹrin ati ọmọ ọdun kan.
Awọn ọmọ yii ni wọn ha si agbegbe ti ẹranko igbo, ejo ati ẹfọn wa.
Aarẹ orilẹede Columbia, Gustavo Petro ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi eleyii to jọ araye loju, ti yoo si wa ninu itan titi lae.
Bi awọn ọmọ naa ṣe gbe ninu aginju...
Awọn ọmọ naa ti wọn wa lati mọlẹbi , Mucutuy mọ nipa aginju, bi wọn ṣe n pa ẹran, bi wọn ṣe n pa ẹja lati kekere.
Baba wọn agba, Fidencio Valencia sọ fun awọn oniroyin pe ẹgbọn wọn agba, Lesly ati eleyii to tẹle, Soleiny mọ nipa aginju naa daradara.
Mọlẹbi wọn obinrin, Damarys Mucutuy sọ fun awọn niroyin pe awọn ti ma n ṣere bi wọn yoo ṣe gbe ninu igbo ‘’survival game’’ lati kekere nitori naa , wọn mọ nipa aginju.
O ni awọn ọmọ naa mọ bi wọn yoo ṣe kọ ile kekere ninu igbo, eso to yẹ ki wọn jẹ ati awọn eso to jẹ majele to wa ninu igbo.
Bakan naa lo ni ọmọ naa mọ lati tọju ọmọ kekere.
Ohun ti Lesly ṣe lẹyin ti ọkọ baalu wọn ja lulẹ ni lati lo igi lati fi kọ ile, ti wọn si lo ohun ti wọn fi n so irun wọn lati fi di papọ.
Bakan naa lo mu flour lati inu ọkọ baalu to ja lulẹ naa ti wọn n wa ninu rẹ alti jẹ.
O ni flour yii ni awọn jẹ titi to fi tan, ki wọn to wa bẹrẹ si ni jẹ eso.
Wọn ni awọn ọmọ naa wa eso lọ si inu igbo eleyii to jẹ avichure, to wa bi kilomita kan si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Onimọ nipa eto idilẹ lorilẹede Coluimbia ni bio tilẹ jẹ pe awọn ọmọ naa ha lasiko ti eso wa loriṣirisi, amọ iyanu nla ni ọrọ naa jẹ bi wọn ṣe gbe ninu aginju naa.
O sapejuwe igbo naa gẹgẹ bi eleyii to kun fun okunkun pẹlu awọn igi nlanla, to fi mọ ojo arọrọda, ati ba wọ ni wọn yoo ṣe ri omi mimu.
Awọn mọlẹbi to ba awọn oniroyin sọrọ ni asiko kan wa ti awọn ọmọ naa ba aja igbo ja, ti wọn si bori rẹ.
Amọ ẹgbọn agba ni imọ nipa aginju lati mọ bi yoo ṣe gbe ni iru agbegbe bẹẹ.
Bi wọn ṣe doola ẹmi wọn...

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ikọ ọmọogun ni bi awọn ṣe n wa awọn ọmọ naa kiri ni wọn n ju awọn iwe pelebe silẹ fun awọn ọmọ naa ti wọn kọ ni ede abinibi awọn ọmọ naa.
Bakan naa ni wọn kọ bi wọn se jajabọ ninu aginju naa.
Amọ awọn ikọ ologun naa ni awọn ti kọja ni ọpọ igba ni agbegbe ti wọn pada ti ri awọn ọmọ naa
O kere tan awọn ikọ ẹṣọ alaabo ti ijọba ati ti awọn ibilẹ to fẹrẹ to igba lo doola ẹmi awọn ọmọ naa.
Akọbi naa nigba to ri awọn to wa doola ẹmi wọn, ohun to kọkọ jade lẹnu ọmọ naa ni pe ebi n pa oun, bakan naa ni aburo rẹ ni iya wa ti ku.
Lẹyin naa ni wọn gbọ pe iya awọn ọmọ naa ku lẹyin ọjọ mẹrin ti baalu naa jabo, to si ni ki awọn ọmọ naa jade kuro nibẹ, ki o to dagbere fun aye.
Ninu ọrọ iya iya wọn, o ni ohun ko fi igba kankan sọ ireti nu fun ogoji ọjọ ti wọn fi n wa awọn ọmọ naa.
Ti wọn si ni igbagbọ pe, iya wọn to doloogbe, lo ni ẹmi airi, to si ri pe awọn ọmọ naa ko bọ sinu ewu.
‘’Àwọn ọ̀mọ̀ mẹ́rin tí wọ́n dóòlà ẹ̀mí wọn nínú agínjú ti rí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn’’

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ọmọ mẹrin ti wọn doola ẹmi wọn ninu igbo aginju ni Columbia ti ri awọn mọlẹbi wọn ni ileewosan ti wọn ti n gba itọju.
Baba agba fun awọn ọmọ naa, Fidencio Valencia lo sọ bẹẹ lasiko ti o ri awọn ọmọ naaa.
Awọn mọlẹbi naa to jẹ ọmọ ọdun mẹtala, mẹsan an, marun un ati ọmọ ọdun kan ni wọn ṣapejuwe pe o ṣi rẹ wọn amọ inu wọn dun lati ri awọn mọlẹbi wọn.
Awọn ọmọ naa n sọrọ diẹ diẹ, ti meji ninu wọn si ti bẹrẹ si ni ṣere.
Ọjọ Ẹti ni awọn ikọ ologun ati awọn ẹṣọ aabo labẹle doola ẹmi awọn ọmọ naa lẹyin ti wọn ti lo ogoji ọjọ ninu aginju.
Iya awọn ọmọ naa ati awọn awakọ baalu meji lo ku ninu iṣẹlẹ naa.
Awọn ọmọ naa ni wọn wa laaye ninu igbo nipa jijẹ eso ati ‘’Flour’’ ti wọn mu kuro ninu ọkọ baalu to jabọ naa.
Awọn dokita wọn ni wọn wa ni alaafia amọ o ṣeeṣe ki wọn wa ni ileewosan fun ọṣẹ meji si mẹta.
Wọ́n tí rí àwọn ọmọ mẹ́rin láàyè, lẹ́yìn Ọjọ́ 40 tí ọkọ̀ bàálù já lulẹ̀ ní aginjù

Oríṣun àwòrán, Reuters
Idunnu ati ayọ sọ ni Columbia lẹyin ti wọn ri awọn ọmọ mẹrin ni wọn ti wọn sọnu si inu igbo ajinju Amazon ni Columbia.
Eyi n waye lẹyin ogoji ọjọ ti awọn ọmọ naa ti jajabọ ninu ijamba ọkọ baalu ni agbegbe naa.
Awọn ọmọ naa lo gbiyanju lati tọju ara wọn ni gbogbo igba ti wọn fi wa ninu igbo naa.
Aarẹ orilẹede Columbia ni awọn ọmọ mẹrin to jẹ ọmọ iya kan naa ni iwalaye wọn jasi ayọ fun gbogbo awọn ara orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ọmọ naa jẹ ọmọ ọdun mẹtala, mẹsan, mẹrin ati ọmọ ọdun kan.
Iya awọn ọmọ naa ati awakọ ofurufu meji lo ku ninu ijamba ọkọ baalu nigba ti o jabọ si inu igbo aginju naa ni Ọjọ Kini, Osu Karun un,ọdun 2023.
Ọgọọrọ awọn soja ati awọn ara agbegbe naa ni wọn bọ si inu igbo lati doola ẹmi awọn ọmọ naa.
Aarẹ naa ni awọn ọmọ naa wa lai si ẹlomiran pẹlu wọn, ti wọn si jajaye, eleyii ti aarẹ naa ni yoo jẹ manigbagbe.
Nibayii, wọn ti ko awọn ọmọ naa lọ si ileewosan fun itọju pipe.
Bakan naa ni awọn mọlẹbi awọn ọmọ naa ni o seese ko jẹ pe idanilẹkọ ti awọn ọmọ naa ni nipa jijẹ eso ati gbigbẹ ninu aginju lo fun wọn ni oye lati gbe ninu aginju naa fun ogoji ọjọ.








