Ìjọba wa kò níí pinwọ́ ìrànwọ́ fún àwọn tí àkọlù ìjọ Saint Francis ṣe àkóbá fún — Akeredolu

Ijọba ipinlẹ Ondo ti ni awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin ati iranwọ to jọju fun gbogbo awọn to farapa ninu akọlu to waye nile ijọsin Saint Francis Xavier nilu Owo lọjọ karun oṣu kẹfa ọdun to kọja.
Gomina Oluwarotimi Akeredolu lo sọ ọrọ yi nibi ayẹyẹ ṣiṣi ile iranti ti ijọ naa kọ lorukọ awọn ti wọn padanu ẹmi wọn sinu akọlu naa.
Akeredolu ti igbakeji rẹ Lucky Aiyedatiwa ṣoju fun wi pe ijọba ipinlẹ lo n sa gbogbo ipa rẹ lati ri pe awọn ti wọn ṣeṣe lasiko akọlu naa ri itọju to pe.
Aiyedatiwa ninu ọrọ rẹ lorukọ gomina wi pe ijọba ipinlẹ Ondo lo ṣe atilẹyin ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta fun ọkọọkan awọn to fara gbọgbẹ ninu akọlu ọun.
Bakan naa lo ni ijọba tun ṣe iranwọ Owo fun awọn mọlẹbi to padanu ẹni wọn lakoko tawọn agbebọn kọlu ile ijọsin naa.
Igbakeji gomina ọun wi pe “ọjọ buruku ni ọjọ naa jẹ ninu akaatan ipinlẹ yi paapaa julọ ti iṣẹlẹ naa waye lakoko ti awọn eniyan n jọsin fun Ọlọrun”.
“Biṣọọbu ti ni a ko wa sibi lati ṣọfọ amọ a ba gbogbo mọlẹbi to padanu awọn ẹni wọn ninu akọlu naa kẹdun a si ki wọn ku ifarada.
“Awọn to ku ti sun ninu Oluwa, awa to ku laye ni ka mura si sisin Ọlọrun ki ọjọ alẹ wa ko le dara.''

“Lati ọjọ ti iṣẹlẹ laabi yi ti ṣẹ ni ijọba ipinlẹ yi labẹ idari Gomina Akeredolu ti bẹrẹ si nii tiraka lati ri pe itọju to peye wa fun awọn to farapa ninu akọlu naa to si tun ṣe isinku to yaayi fun awọn to padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ ọun.
“Koda, ijọba gbe igbimọ kan kalẹ lati boju to itọju awọn to wa laaye ati ipalẹmọ awọn to dagbere faye nipasẹ iṣẹlẹ naa.
“Bakan naa ni ijọba kọ ile iranti kan lorukọ awọn ti iṣẹlẹ naa gba ẹmi wọn, eyi yoo si di ṣiṣi laipẹ ọjọ.
“Ijọba yi yoo tẹsiwaju lati ri pe aabo to daju n wa fun gbogbo olugbe ipinlẹ yi lai fi ti ẹsin abi ẹya ṣe nitori pe ojuṣe ijọba ni lati pese eto aabo to nipọn fun awọn ara ilu.

“Lorukọ ijọba ipinlẹ Ondo, mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn to nawọ si ijọba lati le ṣe eto to yẹ fun awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe akoba fun. Mo si gbaa ladura pe a ko nii ri irufẹ iṣẹlẹ laabi bẹẹ mọ.”
Biṣọọbu ijọ aguda ni daosiisi Ondo, ẹni-ọwọ Jude Arogundade, ninu iwaasun rẹ wi pe apejọ naa kii ṣe lati sunkun abi lati ṣọfọ, bi ko ṣe lati fi han awọn ẹni ibi to wa nidi akọlu naa pe igbagbọ awọn ọmọ ijọ ọun ju ipalara ti akọlu naa ko ba wọn lọ.
Arogundade ni “ijọba ni lati ji giri si didaabo bo awọn ara ilu ki wọn si ri pe awọn to ṣe akọlu naa foju wina ofin ni kiakia.
“Mo layọ lati sọ fun yin pe ọwọ ti tẹ diẹ lara awọn to ṣe akọlu naa ti iwadi si ti de aaye to lapẹẹrẹ.’’

“Mo ni aridaju pe ko si ipenija kan to le mu ki awọn ọmọ ijọ yi o pada lẹyin Ọlọrun. Mo si dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ondo fun atilẹyin ati iranwọ ti wọn ṣe fun ijọ yi ati gbogbo mọlẹbi ti iṣẹlẹ naa ṣe akoba fun.”
Ọjọ Aje, ọjọ karun oṣu yi lo pe ọdun kan ti awọn agbebọn ṣe akọlu si ijọ aguda Saint Francis Xavier ni ilu Owo lakoko isin leyi to mu ẹmi awọn mọkanlelogoji lọ, ti awọn bii marundinlaadọrun si farapa.
Pupọ ninu awọn to farapa ninu akọlu ni oju ọgbẹ ṣi han lara wọn ketekete, ti awọn miran si gba ibẹ di alaabọ ara.












