Bọ́ọ̀sì tó ń bọ̀ láti ayẹyẹ ìgbéyàwó tàkìtì, èèyàn mẹ́wàá jáde láyé

Hunter Valley Accident

Oríṣun àwòrán, EPA

Ko din ni eeyan mẹwaa to ti jade laye, nigba ti awọn marundinlọgbọn mii dero ile iwosan lẹyin ijamba ọkọ ekero kan ni Australia.

Ibi ayẹyẹ igbeyawo lawọn eeyan naa ti n bọ lagbegbe Hunter Valley ki ọkọ wọn to takiti.

Iroyin ni agbegbe Hunter Valley yii jẹ ibi ti ọpọ araalu atawọn arinrinajo afẹ ti maa mu ọti waini.

Ọlọpaa ti fẹsun mẹwaa ọtọtọ kan awakọ bọọsi naa, lẹyin ti wọn ni oun lo ṣokunfas iku awọn eeyan to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Wọn ni awọn ṣi n ṣayẹwo awọn to ku lati mọ irufẹ eeyan ti wọn jẹ.

Amọ tọkọtaya ti wọn lọ ba ṣajọyọ igbeyawo ko si ninu ọkọ akero to ni ijamba.

Kọmiṣọna ọlọpaa, Karen Webb ni wọn ti ko awọn akọṣẹmọṣẹ ọtẹlemuyẹ lọ sibi ijamba ọkọ naa lati tu iṣu de isalẹ ikoko ohun to ṣokunfa ijamba ọhun.

O fi kun pe nnkan bii aago mọkanla abọ alẹ ni ọkọ naa takiti lasiko ti dẹrẹba rẹ fẹ gba ọna obiripo kan.

Ẹwẹ, awọn to farapa ti wa nile iwosan John Hunter bayii nibi ti wọn ti n gbas itọju lọwọ.