Ṣé lóòtọ́ ni NYSC fẹ́ kó àwọn àgùnbánirọ̀ lọ jagun ní Niger? Nnkan tí a mọ̀ rèé

Awọn agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, NYSC

Ajọ to n mojuto eto isinru ilu ni Naijiria, National Youth Service Corps (NYSC) ti sọ pe oun ko ni erongba lati ko awọn ọdọ to n sinru ilu lọ si orilẹ-ede Niger lati ba awọn ologun to gba ijọba jagun, ki ijọba le pada si ọwọ alagbada.

Agbẹnusọ fun NYSC, Ọgbẹni Eddy Megwa, sọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta pe, ayederu ni iroyin to n lọ kaakiri lori ayelujara nipa igbesẹ naa, paapaa fidio kan ti awọn eeyan n pin kiri.

O ni atẹjade naa jẹ dandan gẹgẹ bi esi si fidio kan to n lọ lori ayelujara pe ijọba apapọ fẹ ko awọn to n sinru ilu lọ jagun.

“Ko si otitọ kanakn ninu iroyin naa ti ọkunrin apanilẹẹrin kan gbe sita.

“A fẹ ki awọn to n sinru ilu ati awọn obi wọn fi ọkan balẹ, ki wọn ma si ṣe tẹti si iroyin ọhun to n gbero lati da wahala silẹ.”

Bakan naa lo fikun ọrọ rẹ pe, awọn oṣiṣẹ alaabo yoo mu ọkunrin to ṣe fidio ayederu iroyin naa.

Ọjọ Ẹti to kọja ni Aarẹ Bola tinubu kọ iwe si ile aṣofin fun atilẹyin wọn lati ko ọmọ ogun labẹ asia ajọ Ecowas, lọ si Niger lati fi ipa mu awọn ọmọ ogun to ditẹgbajọba ki wọn o da ijọba pada fun Aarẹ Mohamed Bazoum.

Ṣugbọn ṣa, ile aṣofin ko fi ọwọ si aba naa, wọn si gba a ni imọran pe ki wọn o tubọ tẹsiwaju ninu igbiyanju lati yanju ọrọ naa ni ilana alaafia.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 ni awọn ọmọ ogun kan ni orilẹ-ede Niger, to paala pẹlu Naijiria, gba ijọba lọwọ aarẹ ijọba awaarawa, Mohamed Bazoum.

Lati igba naa si ni Bazoum ti wa ni ahamọ awọn ologun titi di asiko yii.

Lẹyin iditẹgbajọba naa ni ajọ awọn orilẹ-ede to n ṣe ọrọ aje papọ ni Iwọ-oorun Africa, Ecowas, ti n gbiyanju lati da ijọba awaarawa pada.

Amọ gbogbo igbiyanju wọn ni ko tii so eso rere.

Yatọ si eyi, Ecowas, ti Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, jẹ alaga rẹ, fun awọn ọmọ ogun ọlọtẹ naa ni gbedeke ọjọ meje lati da ijọba pada, bi bẹẹkọ, awọn yoo ko ogun ja wọn.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ ni gbedeke naa pari. Amọ titi di asiko yii, ko tii si ohun to jọ pe awọn ọmọ ogun naa yoo tẹle aṣẹ Ecowas.