Haiti earthquake pa èèyàn 304 ilé 1,800 bá ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì lọ ní haiti

Haiti earthquake

Oríṣun àwòrán, facebook: Denver7

Iṣẹlẹ ilẹ riri kan ti gbẹmi eeyan mẹrinleniọọdunrun, ti ọpọlọpọ si fi ara pa.

Ilẹ riri naa waye ni ilu Saint -Louis du Sud, nitosi olu ilu lorilẹ-ede Haiti laarọ ọjọ Satide.

Olootu ijọba orilẹ naa sọ pe yoo gba awọn oṣiṣẹ pajawiri ni nnkan bii oṣu kan lati yanju wahala ti iṣẹlẹ ilẹ riri ọhun da silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdun 2010 ni iru iṣẹlẹ ilẹ riri bayii waye ni Haiti, eyi to pa eeyan bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun, ti ọpọ fi ara pa, ti awọn kan si di alainilelori.

Bakan naa lo tun ṣe akoba fun ọrọ aje orilẹ-ede naa, ti wọn ko si tii pada bọ sipo ki iṣẹlẹ tuntun yii to tun waye.

Ileeṣẹ ilẹ Amẹrika to maa n ṣe iwadii nipa bi oju ọjọ ṣe ri sọ pe ẹgbẹgbẹrun eeyan ni yoo faragba ninu iṣẹlẹ naa.

Ọpọ awọn eeyan lo ti bẹrẹ si n pin oniruru fidio nipa ohun ti oju wọn to lasiko iṣẹlẹ ilẹ riri naa lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Ẹwẹ, olootu ijọba, Ariel Henry sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣe iranwọ fun gbogbo awọn ti iṣẹlẹ naa kan.

O ni ohun to ṣe pataki lasiko yii ni bi awọn yoo ṣe doola awọn eeyan to ha si abẹ awọn ile to wo lulẹ.

Henry ni bo tilẹ jẹ pe awọn ile iwosan ti kun fọfọ fun awọn eeyan to farapa lagbegbe Les Cayes, awọn yoo gbiyanju lati doola ọpọ awọn eeyan miran ni kiakia.