Àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara da ṣẹ́ sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọlọ́jọ́ méjì.

Aworan ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara

Awọn oṣiṣẹ ile-iṣẹ iroyin labẹ lẹgbẹlẹgbẹ oṣiṣẹ awọn ile-iṣẹ iroyin ijọba ipinlẹ Kwara bẹrẹ iyanṣẹlodì onikilọ ọlọjọ meji lonii niluu Ilọrin, olu ìlu ipinlẹ Kwara.

Ipinnu ìyanṣẹlodi naa waye nibi ìpade pajawìrì agbarijọpọ ẹgbẹ oṣìṣẹ ile-iṣẹ ìwe ìroyìn ìjọba ìpínlẹ Kwara (Herald Newspaper), ile-iṣẹ ìgbohunsafẹfẹ ìpínlẹ Kwara ( Radio Kwara), ile-iṣẹ mohunmaworan ìjọba ìpínlẹ Kwara (Kwara TV) ati ile-iṣẹ ọna ati aṣa (Arts and Culture), latarí bí ìjọba ko ṣe dahun ibeere wọn.

Lopin ipade pajawìrì ẹgbẹ awọn oṣìṣẹ awọn ile-iṣẹ ìroyìn naa, ẹgbẹ naa pinnu pe ìyanṣẹlodi oníkìlọ ọlọjọ mejì naa yoo waye lonii ati lọla.

Ninu ifọrọwanilenuwo pẹlu alaga ẹgbẹ akọrọyin ìpínlẹ Kwara, Comrade Lanre Abdullateef ṣalaye pe, lara ohun ti wọn n bere lọwọ ìjọba ìpinlẹ Kwara ni ìṣamuṣẹ ajẹmọnu owo oṣu to kere julọ, ati bi awọn oṣìṣẹ wọn yoo ṣe máa de ìpele ìkẹtadínlogun lẹnuṣẹ ọba bii ti awọn akẹgbẹ wọn to ku lẹnusẹ ọba ( level 17).

Wọn tun bere fun ki ijọba fopin si yíyan akọwe fun wọn lati ile-iṣẹ mii.

Wọn tun bere fun atunṣe awọn ile iṣẹ ìroyìn to jẹ ti ìjọba ipínlẹ Kwara, pẹlu ìpese awọn ohun elo igbalode.

Ìṣamuṣẹ ìgbega lẹnuṣẹ fawọn ọṣìṣẹ tọdun 2021 ati 2022. Iṣamuṣẹ ìda ọgọrun-un awọn oṣìṣẹ alakanṣe ( Essential workers ).

Lasìko ti asojukọrọyin BBC n fọrọ wa akọwe ẹgbẹ akọrọyìn ile-iṣẹ Radio Kwara Saheed Abdullahi ati akọwe ẹgbẹ RATTAWU ile-iṣẹ Radio Kwara Arabìnrin Funmilayọ Àìná lẹ́nu wò, wọ́n sàlàyé pé, ìyanṣẹlodì naa n tẹsiwaju lọla, nitori ìpade ti wọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ìjọba ko ṣe so re.

Lasìko to n sọrọ akọwe eto ìroyìn ìjọba ìpínlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye jẹ ko di mímọ pe, ìdahun si ìbeere wọn yoo wa nínu eto ìṣuna ọdun to n bọ.