Ọwọ́ tẹ adigunjalè kan n'Ilorin, ìyá rẹ̀ bá dákú rangbọndan

Aworan ile ti adigundale ja

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹni to ba kan nikan lo le ṣapejuwe iru ibanujẹ to wa lọkan iya naa ti ọpọ mọ si Iya Joshua latigba ti ọwọ ti tẹ ọmọ ẹ, ti wọn fẹsun ile fifọ kan.

Afurasi adigunjale naa ni orukọ rẹ n jẹ Mathew lagbegbe Danialu Gaa Akanbi, to si jẹ olugbe n'iluu Ilorin, ipinlẹ Kwara.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila yii ni ọwọ tẹ Mathew lasiko to n gbe gbiyanju lati jalẹ.

Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe nnkan bii aago marun-un kọja iṣẹju diẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ni ọwọ palaba Mathew sẹgi lasiko to lọọ jale nile Kabiru ti o jẹ onisẹ ọwọ.

Awọn ọdọ agbegbe naa si tun ri Kabiru gẹgẹ bii olori ọdọ.

Ọkan lara olugbe agbegbe naa, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, sọ pe, Mathew ṣe akiyesi si pe Kabiru ti jade kuro nile, lo ba ja nẹẹti oju ferese, o fẹ irin bọgilari, o si pọ gbabẹ wọle.

Ni kete to wọle tan ni Kabiru dari wọle lati mu nkan to gbagbe, sugbon ọbẹ ni afurasi Mathew fi pade rẹ, Kabiru sa jade, o si pariwo ole.

Ni isẹju aaya ni awọn ọdọ agbegbe naa yi ile ka, wọn si duro ni isọri isọri, Mathew ba sa gun aja ile lọ pẹlu ọbẹ lọwọ, loba ku aja ti yoo wọle tẹkun, lati wọọ jade.

Ẹni akọkọ to gun aja, Mathew fi ọbẹ see lese titi de ori eeyan kẹta. Lẹyin ọrẹyin, wọn wọ Mathew jade pẹlu ipalara ọbẹ to fi gun wọn ti ẹjẹ si n se yọbọ lara wọn.

Ibi ti wọn ti n luu bi ejo aijẹ ni o ti yọ bọ pọrọ mọ wọn lọwọ, lo ba n sa lọ, sugbọn awọn ọdọ yi gba tẹle, wọn si n le e titi wọn fi le e de ile wọn to n gbe ti ko jina pupọ sibi to ti lọọ jale.

Bi Mathew ṣe sa wọ ile wọn ni awọn ọdọ yii raamu, ti wọn si ja silẹ nihoho wọn lu u ti ẹjẹ ṣe n jade ni gbogbo ara rẹ.

Lasiko ti wọn n lu Mathew lọwọ ni iya afurasi yii daku rangbọndan to si lo to bii ọgbọn iṣẹju ko to pada saye.

Koda awọn kan ti gbe epo bẹntirolu jade lati dana sun un sugbon o jọla awọn ọlọpaa ti wọn de, wọn si faa afurasi Mathew le wọn lọwọ.

Ki ni ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?

BBC Yoruba ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, ASP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun sọrọ lori isẹlẹ naa, o si fidi rẹ mulẹ.

O ni loootọ ni wọn mu ọmọkunrin kan wa lati agbegbe Danialu Gaa Akanbi, n'ilu Ilọrin, ti wọn ni o jale ti wọn si ti lu u ba jẹ.

Sugbọn ko si ẹni to wa si ileeṣẹ ọlọpaa lati igba ti wọn ti mu u wa lati wa sọ irufẹ nnkan to ji gbe.