Ọgbọ̀n ọdún ni mo lò ní UK àti Amẹrika àmọ́ kòròfo ni mo padà wá sí Naijiria

Oríṣun àwòrán, Fatteh Hamid/Punch
Baba ẹni ọdun mejidinlaadọrin kan, Joseph Ibironke, ti ṣalaye pe lojiji ni oun ṣadede ba ara oun ni Naijiria lẹyin ti oun ti lo ọpọ ọdun loke okun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọdun mẹsan an ló lò nilẹ Gẹẹsi, ko to tun lọ lo ọdun mọkanlelogun mii nilẹ Amẹrika, amọ korofo lo pada mu wale.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch ni ọkunrin ọhun ti tu pẹrẹpẹrẹ iriri rẹ.
Ọgbẹni Ibironke, to jẹ ọmọ ipinlẹ Ondo ṣalaye pe oun kawe gboye ni Naijiria ki oun to tẹkọ leti lọ si oke okun.
Bi irinajo naa ṣe bẹrẹ
Ibironke sọ pe iṣẹ ẹṣọ alaabo ni oun ṣe ni UK ati Amẹrika ki nnkan to yiwọ fun oun.
O ni ileeṣẹ Burns International Security Services Limited, ni UK ni oun ti kọṣẹ eto abo, nigba ti oun si de ilẹ Amẹrika, oun ṣiṣẹ pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI fun igba diẹ ki Ọlọrun to pe oun si iṣẹ iranṣẹ.
“Mo ni ile itaja nla kan ni Orange County, ni California nibi ti ọpọ awọn alawọ funfun n gbe, koda mo ti n rinrinajo lọ si orilẹ-ede Japan, nibi ti mo ti maa n lọ ko ọja lati ta l’Amẹrika.
“Emi nikan ni alawọ dudu to lọla julọ lagbegbe Orange County lasiko naa.”
Ọkunrin ọhun sọ pe oun ni iyawo l’Amẹrika, pẹlu ọmọ mẹrin ṣugbọn oun ko mọ ibi ti wọn wa bayii.”
Bi irinajo pada si Naijiri ṣe jẹ
O tẹsiwaju pe lasiko kan ti oun n mura lati pada si Naijiria ni aisan kan dede kọlu oun.
“Iyawo mi sọ fun mi pe loru ọjọ kan, lẹyin ti a ṣere ololufẹ tan ti a sun ni mo bẹrẹ si n gbo bii aja.
“O ni ẹru ba oun, pe wọn gbe mi lọ sile iwosan nibi ti mo ti lo oṣu mẹrinla amọ awọn dokita ni awọn ko ri ohun to n ṣe mi.
“Awọn ọmọ Naijiria to wa nibẹ lo mu imọran wa pe aisan naa kii ṣe oju lasan, wọn si ni ki n lọ gba itọju ni Naijiria.”
Ọkunrin ọhun ṣalaye siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe oun ko mọ bi oun ṣe de Naijiria, nigba ti oun de Naijiria, ile iwosan awọn alaarun ọpọlọ to wa ni Yaba, niluu Eko lawọn ẹbi oun gbe oun lọ, ti wọn si fi oun silẹ nibẹ lai bẹ oun wo.
O ni nigba to pẹ ni awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa le oun jade, lẹyin naa ni awọn kan gbe oun lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri latari bo ṣe n rin kiri aarin igboro.
Lẹyinorẹyin, ọkunrin naa di ẹni to n sun abẹ afara Oshodi ki iye rẹ to ṣi.
Wayi o, o ti ni afojusun oun ni lati pada silẹ Amẹrika nibi ti iyawo ati ọmọ oun wa.














