Egungun èèyàn 102 kán nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin

Oríṣun àwòrán, screeshot/reuters
Ko din ni eeyan mejilelọgọrun, ti egungun ara wọn kán , lẹyin ti ọkọ oju’rin meji kọlu ara wọn niluu Beijing.
Eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹta si lo di eero ileewosan lẹyin ijamba naa to waye ni nnkan bi aago meje alẹ Ọjọbọ.
Ileeṣẹ iroyin orilẹ-ede China sọ pe awọn ọkọ oju’rin mejeeji fi ori gba ara wọn lasiko ti yìnyín n jabọ, nibi ti wọn ti n sọkalẹ ori oke kan to wa ni oju ọna reluwe Changping.
Nigba ti yoo si fi di owurọ ọjọ Ẹti, eeyan 423 ti gba itusilẹ kuro nileewosan.
Botilẹ jẹ pe iru ijamba naa ko wọpọ ni olu ilu china, yinyin to n jabọ lasiko mu ki awọn oju ọna reluwe ko ma a yọ̀.
Idaru-dapọ to ba awọn ẹrọ to ma n fun awọn awakọ reluwe ni ami, lo mu ki ọkọ oju’rin akọkọ tẹ ijanu rẹ lojiji.
Ọkọ oju’rin to tẹle naa ko tete tẹ ijanu rẹ nigba to n sọ kalẹ bọ si ori reluwe to kun fun yinyin, eyi to mu ko kọlu ọkọ oju’rin akọkọ lati ẹyin.
Ijamba naa mu ki meji lara awọn ile ijoko si awọn eero ọkọ ja lulẹ lara ọkan ninu ọkọ oju’rin mejeeji.
Ninu awọn fidio to wa lori ayelujara nipa ijamba naa, niṣe ni awọn eero kan n gbiyanju lati fi oolu (hammer) fọ gilaasi oju ferese ọkọ jade fun afẹfẹ.

Oríṣun àwòrán, weibo
Inu okunkun birimu si ni awọn eeyan wa ninu awọn ọkọ naa nitori bi ina ẹlẹtiriiki ṣe ku.
Bakan naa ni fidio kan ṣafihan obinrin kan to ti daku, ti wọn si tẹ ẹ si ori awọn aga ijoko ninu ọkọ oju’rin kan.
Eeyan mẹtadinlaadọrin lo ṣi n gba itju nileewosan, mẹẹdọgbọn si wa ni abẹ amojuto to l’agbara.
Amọ, ko si ẹnikẹni to kú ninu ijamba naa.
Oriṣiriṣi ariyanjiyan si lo ti n waye lori ijamba naa lati ọdọ awọn ọmọ orilẹ-ede China.
Ijọba ẹkun Beijing lo ni oju ọna reluwe naa ati awọn ọkọ rẹ to n na agbegbe mẹtadinlọgbọn.
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ reluwe naa si ti tọrọ aforijin. Bakan naa ni wọn ni awọn yoo san owo itọju gbogbo awọn to farapa.
Yatọ si eyi, wọn tun ti tun ilana ati akoko ti awọn ọkọ oju’rin n ṣiṣẹ tò.
Yinyin to n jabọ ni Beijing ti da nnkan ru ni ẹka irinna oju popo, reluwe ati ofurufu.
Awọn onimọ nipa oju ọjọ si ti kilọ pe otutu yoo tubọ mu si i lati Ọjọbọ titi di ọjọ Aiku.
Koda, awọn alakoso ti ti awọn ile ẹkọ pa ni awọn ilu kan, ti wọn si tun da irinajo ọkọ reluwe duro.














