Ilé wó pa ìyá àti ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìkómọ rẹ̀ nílùú Akure

Yoruba bọ wọn ni, a ki i sun nile ẹni ki a fi ọrun rọ, amọ, ọrọ ko ri bẹ fun obinrin kan to ṣeṣẹ bimọ ikoko ni agbegbe Ayedun, niluu Akure, nipinlẹ Ondo.
Obinrin naa ti wọn ṣe ikomọ ọmọ rẹ lanaa ọjọ Iṣẹgun ni ile wo pa oun ati ọmọ rẹ ti wọn fun ni orukọ lanaa.
Lara awọn o ṣoju mi koro ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe o to wakati kan lẹyin ti ile naa ti dawo ki wọn to ri obinrin ati ọmọ rẹ naa yọ jade labẹ rẹ.
Ẹni to ba BBC Yoruba sọrọ naa sọ pe tanki omi lo ṣekupa obinrin ọhun ati ọmọ rẹ nigba ti ile naa dawo.
Obinrin ọhun fikun ọrọ rẹ pe obinrin naa fẹ wẹ fun ọmọ rẹ ni ile ọhun dawo.
A gbọ wi pe awọn ọlọpaa lo wa palẹ oku obinrin naa ati ọmọ rẹ mọ.
Oriṣiriṣi ẹru ọmọ atawọn nkan iṣere ọmọ lo wa nibi ti ile naa ti wo.
O ṣoju mi koro miran tun sọ fun BBC Yoruba wi pe baba ọmọ ikoko yii gan an ko ti i foju ri ọmọ naa ti wọn fi ṣagbako iku ojiji.
Iṣẹ ọlọpaa kogberegbe ni a gbọ pe baba ọmọ naa n ṣe, eyi ti ko fun un ni aye lati foju kan ọmọ yii titi ti o fi jade laye pẹlu iya rẹ nibi iṣẹlẹ laabi naa.
Ẹlomiran to tun ba BBC Yoruba sọrọ nibi iṣẹlẹ ọhun sọ pe ile ijọsin kan naa ni oun ati ọmọ ikoko to ku yii jọ n lọ.
Bakan naa ni obinrin ṣalaye pe ile to dawo yii ti n fi apẹẹrẹ han tẹlẹ pe o le wo lulẹ nigba kugba.
A tun gbọ pe ori lo ko iya ati akọbi ọmọ obinrin to ṣẹṣẹ bimọ yii yọ ninu iṣẹlẹ naa, koda wọn ni awọn mejeeji farapa diẹ.
Obinrin kan toun naa ba BBC Yoruba sọrọ ṣapejuwe abiamọ to ku yii pẹlu ọmọ rẹ pe jẹjẹ rẹ lo maa n lọ ki i ba ẹnikẹni ja.
Obinrin yii ni ibanjẹ nla gbaa ni iṣẹlẹ yii jẹ fun oun.















