Iléeṣẹ́ bàlúù tó bá pẹ́ kó tó gbéra yóò máa sanwó gbà má bínú fáwọn arìnrìnàjò - Keyamo

Aworan baluu to fẹẹ gbera ati Festus Keyamo

Oríṣun àwòrán, GETTY

Awọn ileeṣẹ to n fi baalu ṣeto irinna ni wọn yoo bẹrẹ si nii san owo gba mabinu fawọn arinrinajo ti baalu wọn ba da irinajo duro tabi ti wọn ko ba tete gbera.

Minisita feto irinna ọkọ ofurufu lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo, lo sọ eleyi lọjọ Iṣẹgun nigba to fara han niwaju igbimọ ile aṣofin apapọ ilẹ yii lori irinna ofurufu lati sọrọ gbe eto iṣuna ileeṣẹ rẹ fun ọdun 2024.

Keyamo wi pe gbogbo baalu to ba pẹ ko too gbera tabi ti ko lee ri irinajo rẹ rara ni ileeṣẹ ohun yoo maa fi orukọ wọn lede lọsẹẹsẹ.

O wi pe “mo ti pe igbimọ to n moju to itẹlọrun awọn onibara lori bi awọn baalu ṣe n ṣe awọn ọmọ Naijiria, koda, mo ti pada yọju si wọn, ki ẹ lee mọ bi ọrọ naa ṣe ka mi lara to.

“Mo sọ fun wọn nibi ipade awọn alẹnulọrọ taa ṣe l’Eko ati ni Warri pe gbogbo ọsẹ ni ki wọn maa fi orukọ awọn baluu ti ko ba gbera lakoko to yẹ, eyi to ba fagi le irinajo, eyi to ba pẹ ki wọn too gbera ati oye wakati to fi pẹ lede, ki wọn si sọ boya wọn san owo gba ma binu ati ohun ti igbimọ naa ṣe fun ileeṣẹ to ni baluu naa. Gbogbo eleyi yoo si bẹrẹ loṣu kini ọdun 2024.”

Keyamo wi pe “fun gbogbo idaduro, akọọlẹ wa amọ ki ni awọn alamojuto n ṣe pẹlu akọọlẹ yii? Ṣe wọn san owo gba ma binu? Ti wọn ko ba san an, ọna miran ni lati wa ti wọn yoo fi pẹtu si onibara wọn lọkan.

“Ọna miran ti wọn lee lo ni lati ta tikẹẹti ti wọn ba fẹẹ ra lọjọ iwaju ni ẹdinwo bii ida aadọta abi ogoji ninu ọgọrun.

‘Awọn oludokoowo lo lee tun papakọ ofurufu wa ṣe ko rẹwa’

Keyamo fi kun pe ọna to dara julọ lati mu agbega ba awọn papakọ ofurufu ni Naijiria ni lati tọwọ bọ iwe adehun pẹlu awọn oludokoowo

“Awọn aladani ni lati dasi ọrọ naa. Ko si iyemeji lori eleyi tori pe a ko ni owo lọwọ lati ṣee.

“Ti a ba fẹẹ tọwọ bọwe adehun pẹlu awọn oludokowo yii, awa la maa fun wọn ni ohun ti a n fẹ, kii ṣe ohun ti wọn ba n fẹ. A ni lati fẹnu ko siru ifọwọsowọpọ ti a n fẹ.

“A fẹẹ tẹsiwaju ṣugbọn mo fẹ ki gbogbo wa o joko wo awọn ti o dara julọ, bo rilẹ jẹ pe a ni lati rin de opin aye ki a too ri wọn. Awọn to wa nipo kini la ni lati mu wa kii ṣe awọn onipo keji. Awọn onipo kini lo lee bawa tun ilẹkun abawọle wa ṣe.”