Ojúṣe wa ni ká dáàbò bo àwọn ọmọ Naijiria, kìí ṣe ká pa wọ́n - Iléèṣẹ́ ológun

Baalu ileesẹ ologun

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN AIR FORCE HQ/FACEBOOK

Ọga Agba nileeṣẹ ologun orile-ede Naijiria, Ọgagun Christopher Gwabin Musa, ti sọ pe, ibanujẹ ni iṣẹlẹ to waye niluu Tudun Biri, nipinlẹ Kaduna, jẹ fun awọn.

Ileeṣẹ ologun sọ pe eeyan mọkanlelọgọrin ni aṣita ado oloro naa pa.

Saaju ni Ajọ to n ri si isẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria ti kede pe eeyan marundinlaadọruun lo ba isẹlẹ naa lọ, ti awọn ẹgbẹ mi si ni iye naa ju bẹ lọ.

Ọgagun Gwabin sọ ọrọ ibanikẹdun níbi ipade to ṣe pẹlu awọn akọroyin, ni olu ileeṣẹ ologun to wa niluu Abuja.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ni baalu to n ṣe alamí (drone) fun ileeṣẹ ọmọ ogun, ju ado oloro meji si aarin àwọn eeyan to kora jọ fun ìsìn Maulud, ni ijọba ibilẹ Igabi.

Iṣẹlẹ naa fa iwọde alagbara ni agbegbe naa, ti ọpọ ọmọ Naijiria naa si koro oju si i.

Ọga agba ologun sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa ko boju mu, o ni sugbọn irọ ni iroyin ti awọn kan n sọ kiri pe, nitori awọn ìdí bi ọrọ ẹsin,, ni awọn ṣe ṣe ikọlu naa.

Ọgagun Christopher Musa Gwabin sọ pe "Ọlọrun to da awa ọmọ Naijiria, ko ko wa jọ pọ nitori ka le pa ara wa run". Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni nnkan to ma n mu ki iṣọkan wa ni aarin ilu, paapaa nibi ti ẹsin ati àṣà wọn ti yatọ ni pe, òye aye ye wọ́n, wọn si mọ ibukun ti Ọlọrun fun ẹni kọọkan. O ni awọn ti n gbe igbesẹ lati ri i daju pe ileeṣẹ ologun ko ṣe iru aṣiṣe bẹẹ mọ. Ṣaaju ni ileeṣẹ ologun sọ pe awọn kẹẹfin awọn janduku, ni awọn fi ju ado oloro.

'Atunse yoo bẹrẹ laarin ọsẹ mẹta si asiko yii'

Igbakeji aarẹ, Naijiria, Kashim Shettima, ṣe abẹwo si awọn to farapa ninu ikọlu naa
Àkọlé àwòrán, Igbakeji aarẹ, Naijiria, Kashim Shettima, ṣe abẹwo si awọn to farapa ninu ikọlu naa

Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa lẹyin to waye, o si kede ni ọjọ diẹ lẹyin rẹ pé, ipinlẹ naa yoo bẹrẹ si ni se atunse si ilu Tudun Biri. O si fi da awọn araalu pe Igba keji Aarẹ ti ṣe ileri lati jẹ ko waye . “Isẹlẹ to wa yii, a ti gbe igbimọ kalẹ , gbogbo ilu naa ni a yoo tun kọ.” “Igbakeji Aarẹ ti pe mi, o si fi da mi loju pe sise atunse si ilu naa yoo bẹrẹ ni aipẹ."