Ecowas yọ Niger kúrò lájọ náà títí di ìgbà tí yóò fi dá ìjọba padà fún alágbádá

Oríṣun àwòrán, others
Ajọ orilẹede lẹkun iwọ oorun Afirika, Ecowas ti fa iwe ọmọ ẹgbẹ orilẹede Niger lajọ naa ya. Ajọ naa ni ki orilẹede Niger lọ rọọkun nile fun igba kan na titi ti wọn yoo fi tu aarẹ orilẹede naa ti awọn ologun yẹ aga mọ nidi, Mohammed Bazoum silẹ.
Ni oṣu keje ọdun 2023 lawọn ologun gba ijọba mọ Aarẹ Bazoum lọwọ lasiko iditẹgbajọba to waye nibẹ.
Ajọ Ecowas ṣalaye ninu atẹjade kan ni Ọjọbọ wi pe, ohun ti ipade awọn olori orilẹede labẹ ajọ naa to waye laipẹ yii fi ẹnu ko le lori ni pe, nṣe lawọn ologun ditẹ gba ijọba lọwọ Aarẹ Bazoum.
Ecowas wa yọ̀ ọwọ orilẹede Niger kuro lawo awọn igbimọ to lẹnulọrọ ni ajọ naa titi di igba ti awọn ologun yoo fi da ijọba pada fun alagbada lorilẹede ọhun
Ṣaaju akoko yii, ohun ti ajọ Ecowas duro le lori ni pe iditẹgbajọba ti ko tii kẹsẹ jari lo waye lorilẹede Niger, pẹlu erongba ati da aarẹ Bazoum pada si ipo, eleyi lo si n faa lọwọ sẹyin lati fa iwe ọmọẹgbẹ rẹ ya lajọ naa.
Nigba ti iditẹgbajọba yii kọkọ waye loṣu keje, ajọ Ecowas kọkọ fi oniruru ofin de awọn olori ijọba ologun lorilẹede Niger ti wọn si tun lerileka pe awọn yoo ko ogun ja orilẹede naa.










