Àjọ̀dún ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ kọlu ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers, àwọn kọmíṣọ́nà ń kọ̀wé fipò sílẹ̀ ní ṣísẹ̀ n tẹ̀lé

Aworan gomina Fubara ati Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, others

Wahala to n waye laarin minisita olu ilu Naijiria, Nyesom Wike ati gomina ipinlẹ Rivers, Fubara tun gba ọna ara yọ pẹlu bi awọn kọmiṣọna mẹta ọtọọtọ ninu igbimọ isakoso ijọba ipinlẹ naa ṣe kọwe fipo silẹ ni ṣisẹ n tẹle laarin wakati mẹrinlelogun sira wọn

Amofin agba, to tun jẹ kọmiṣọna feto idajọ, Ọjọgbọn Zacchaeus Adangor lo kọkọ kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Aworan Ojogbon Zacchaeus Adangor

Oríṣun àwòrán, Zacchaeus Adangor

Adagor ni ipinnu ọkan lo mu ki oun gbe igbesẹ fifi ijọba Fubara silẹ.

Nigba to di ọjọbọ ni kọmiṣọna fun iṣẹ ode ni ipinlẹ naa, George-Kelly Alabo naa ba tun kọwe fipo silẹ, ti akẹgbẹ rẹ fun igbayegbadun araalu, Inime Aguma pẹlu tun ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Aworan George-Kelly Alabo

Oríṣun àwòrán, George-Kelly Alabo

Ninu lẹta to kọ lati fi ipo silẹ, Ọgbẹni Alabo ni oun gbe igbesẹ lati fi igbimọ ijọba gomina Fubara silẹ nitori “ẹri ọkan igbagbọ ọkan ẹni ati ofin to de iṣẹ ti oun yan laayo.”

Ninu lẹta ti oun naa kọ si gomina ipinlẹ Rivers lati fi ipo silẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna fun igbayegbadun araalu, Arabinrin Aguma ni awọn eto kan ti oun n ṣe lọwọ lo fa a ti oun fi yọwọ kuro ninu awo iṣejọba ni ipinlẹ.

Kọmiṣọna fun eto iṣuna, Isaac Kamalu, pẹlu ti kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Amọṣa Isaac Kamalu ni tirẹ ko sọ ohun to wa nidi igbesẹ rẹ

Ina ko wọ laarin erin meji lagbo oselu Rivers

Aworan Inime Chinwenwo Aguma

Oríṣun àwòrán, Inime Chinwenwo Aguma

Ọrọ ko wọ laarin Wike ati Fubara lagbami oṣelu ni ipinlẹ Rivers.

Tirela gba aarin awọn mejeeji kọja laipẹ pupọ ti iṣejọba tuntun bẹrẹ loṣu karun un ọdun 2023.

Ṣaaju ni ọsẹ yii lawọn aṣofin mẹtadinlọgbọ ni ipinlẹ naa kede pe awon ti ya kuro lẹgbẹ oṣelu PDP lọ si APC ki adari ile naa to kede aga wọn gẹgẹ bi eyi to ṣofo.