Makinde fi Asẹyin ti ilu Iṣẹyin tuntun jẹ

Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Aṣẹyin tuntun

Oríṣun àwòrán, tvc

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti gbe ade le Asẹyin tuntun fun ilu Iṣẹyin, Ọba Sefiu Oyebola Adeyeri III, lori.

Ilu Iṣẹyin ni ayẹyẹ igbade naa ti waye, lọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Nibi ayẹyẹ naa ni awọn ọmọ ilu Iṣẹyin ti korajọ pọ lati gba ọba wọn tuntun.

Lati bi ọdun kan aabọ ni ipo ọba ti ṣofo niluu Isẹyin, lẹyin iku Ọba Abdul-Ganiyu Salawudeen Adekunle lẹyin ọdun mẹẹdogun to jọba.

Ọba tuntun, Adeyeri III si lo wa ni ipo ọgbọ̀n ninu awọn Aṣẹyin to ti jẹ.

Ninu ọrọ to sọ lẹyin ti gomina gbe ade le e lori, Ọba Adeyeri sọ pe awọn nnkan ti araalu n fẹ ni yoo jẹ afojusun oun lori itẹ, ati lati mu idagbasoke wọ ilu lasiko rẹ.

Bakan naa ni Gomina Makinde ninu ọrọ tiẹ naa kilọ fun awọn ọba to n lo ipo wọn lati ṣe atilẹyin fun awọn to n wa alumọọni ilẹ lọna ti ko ba ofin mu.

Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, ni Ọba Sefiu Oyebola Adeyeri III, pari gbogbo etutu ati eto to yẹ ko ṣe , ko to o jọba.

Ṣugbọn ṣa, amofin kan, Abideen Adeniran, fi ikilọ sita fun Gomina Seyi Makinde lọjọ Aiku to kọja, pe ko gbọdọ fi ọba na jẹ.

Iwe iroyin Punch jabọ pe oun sọ bẹẹ nitori ẹjọ to n lọ lọwọ lori ọrọ oye Aseyin, ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo,

Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Asẹyin

Oríṣun àwòrán, tvc

Asẹyin tuntun n ka ọrọ akọsọ

Oríṣun àwòrán, tvc

Ilẹ America ni Ọba Olawale Sefiu Oyebola n gbe ṣaaju ki wọn o to yan an gẹgẹ bi Aṣẹyin tuntun.

Awọn ọmọ igbimọ afọbajẹ yan Oyebola, ti i ṣe ẹni ọdun bii marundinlọgọta, lai si atako kankan lati ọdọ wọn.