Kí ló mú kí Timi ilẹ̀ Ede àtàwọn Olorì rẹ̀ kópa nínú sinimá àgbéléwò? Àlàyé rèe

Àkọlé fídíò, Kí ló mú Timi Ede àtàwọn Olorì rẹ̀ kópa nínú sinimọ́ àgbéléwò?
Kí ló mú kí Timi ilẹ̀ Ede àtàwọn Olorì rẹ̀ kópa nínú sinimá àgbéléwò? Àlàyé rèe
Aworan Timi Ilẹ Ede ati awọn Olori

Ọpọ eeyan lo n woo wi pe ki lo le mu ki odidi ọba alaye bi Timi ilẹ Ede, Ọba ati Ọmọwe Munirudeen Adeṣọla Lawal lati kopa ninu sinima agbelewo, lẹyin ti ọba alaye yii atawọn olori wọn kopa ninu sinima kan ti akori rẹ n jẹ ‘’Ẹbi Tayese.’’

Ẹni to ṣagbatẹru sinima ọhun, Ọlanrewaju Ṣarafa, ti gbogbo aye n pe ni ‘Tayeṣe of London' ṣalaye bi ọba alaye yii atawọn olori rẹ ṣe wa lara awọn to kopa ninu ere naa.

Ọgbẹni Sarafa to n gbe nilu Oyinb ṣugbọn to jẹ ọmọ bibi ilu Ọṣun ni igbelarugẹ aṣa Yoruba ni idi abajọ ti Timi ilẹ Ede atawọn Olori rẹ fi kopa ninu ere yii.

Sarafa ni ‘’ṣe ẹ ri ninu sinima yii, ohun naa ni a ti gbe.

Ọba ọlọla nla dide, iyẹn Timi ilẹ Ẹdẹ,ati awọn Olori wọn mejeeji, wi pe ki awọn naa kopa nibi ki aṣa Yoruba ko ma parun.’’

Kabiyesi naa sọ pe ‘’ninu ọmọ ti o yanju ti o jẹ to jẹ ololufẹ Yoruba, ti o tun wa ka aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, to tun dii mu, oun ni Sarafa jẹ.

Bi iru rẹ ba wa n ṣe akitiyan lati gbe aṣa larugẹ, to jẹ pe awa Ọba gan an ni a wa ni igbọnu ki a mojuto aṣa, ti a tun wa ri ẹnikan to ba wa gbee ni igbọnwọ, inu eeyan yoo dun lati dide si iru ẹni bẹẹ.

Ohun ni mo fi dide, ni gbogbo ilu fi dide,

ni awọn Olori naa fi dide, lati jẹ ki a gbe aṣa iṣẹ ilẹ Yoruba wa larugẹ.