Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ awuyewuye, Aiyedatiwa di adelé gómìnà l’Ondo

Aworan Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/HON. LUCKY ORIMISAN AIYEDATIWA

Abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ondo ti kede pe igbakeji gomina ipinlẹ naa, Lucky Aiyedatiwa, ti di adele gomina lati oni, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun 2023, titi di ọjọ ti Gomina Oluwarotimi Akeredolu yoo pada de lati isinmi to lọ.

Abẹnugan ile ọun, Olamide Oladiji, lo sọ eleyi ninu lẹta kan to fi soju opo atẹjiṣẹ WhatsApp, lẹyin ti agbẹnusọ ile, Olatunji Oshati, ti fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba.

Oladiji wni “ni atẹle amọran dokita pe ki Gomina Oluwarotimi Akeredolu o lọọ sinmi lẹyin ti alaafia ti n de sagọ ara rẹ, gomina naa lo ti fiwe ṣọwọ sile aṣofin lati fi to wọn leti pe oun n lọ fun isinmi.

“Gẹgẹ bi lẹta ọhun ṣe wi, igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa, ni yoo maa ṣe ojuṣe gomina bii adele titi di igba ti iwe miran yoo de latọwọ gimnina pe ko ri bẹẹ mọ.

“Isinmi yi ni ireti wa pe yoo bẹrẹ lọjọ kẹtala oṣu kejila, ọdun 2023.”

Oladiji fi kun un pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun alaafia to de sagọ ara gomina ni kia ati pe oun nigbagbọ pe yoo pada sẹnu iṣẹ laipẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, awuyewuye ti n waye lori ipo ti ilera gomina Akeredolu wa.

Ṣaaaju ni Akeredolu ti kọkọ tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede Germany, nibi to ti lọ gba itọju aisan kan ti ko darukjọ fun awọn ọmọ ipinlẹ Ondo.

Asiko to kọkọ lọ gba itọju naa ni o fa ijọba kalẹ fun Aitedatiwa.

Amọ ni kete to de lati irinajo ni o gba iṣẹ lọwọ awọn agbenusọ igbakeji rẹ, ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa si gbiyanju lati yọ Aiyedatiwa nipo bii jiga ko to tọrọ aforiji lọwọ gomina.