Wo iye ọmọ Nàìjíríà tó ń ta tẹ́tẹ́ lójúmọ́

Awọn eeyan ni ibudo tẹtẹ tita

Oríṣun àwòrán, others

O le ni ọgọ̀ta miliọnu ọmọ Naijiria ti wọn n ta tẹtẹ loriṣiriṣi bayii.

Ajọ to n ṣe kokari abo data lorilẹede Naijiria, NDPC lo sọ eyi.

Ọga agba ajọ naa, Ọmọwe Vincent latunji lo kede eyi lasiko to fi n dahun ibeere lori eto kan ni ileeṣẹ mohunmaoran Channels, ọkan lara awọn ileeṣẹ iroyin abẹle lorilẹede Naijiria.

Ọmọwe Ọlatunji to ṣalaye pe ajọ naa n sa gbogbo ipa ni ajọṣepọ pẹlu awọn aj gbogbo lorilẹede Naijiria lọna ati rii pe abo to peye wa fun akọsilẹ awọn eeyan lori ayelujara.

O ni awọn ajọ bi Banki apapọ, CBN ajọ ibaraẹni sọrọ ni Naijiria, NCC ati bẹẹbẹẹ lọ sọrọ lọna ati da abo bo awọn akọsilẹ araalu lẹka ifowopamọsi ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ lorilẹede Naijiria.

Awọn akọsilẹ nipa tẹtẹ tita ni Naijiria

Aworan eeyan kan to fẹ ta tẹtẹ

Oríṣun àwòrán, others

Laarin ọdun kan nnkan bii biliọnu dọla ni awọn eeyan n na lori tẹtẹ ere idaraya tita.

Bẹẹni lapapọ, ẹgbẹrin mẹta Naira ni ọmọ Naijiria kọọkan to n ta tẹtẹ n fi ta tẹtẹ lojumọ

Apapọ iwadi fihan pe ida mẹtalelaadọta (53%) ọmọ Naijiria lo n ta tẹtẹ lojumọ.