Lórí ikú Mohbad, Naira Marley fẹ́ pe Iyabo Ojo, ìwé ìròyìn Punch àti àwọn mìí l'ẹ́jọ́

Aworan Naira Marley ati Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/NAIRA MARLEY/IYABO OJO - QUEEN MOTHER

Gbajugbaja olorin takasufe, Afeez Fashola, ti gbogbo aye mọ si Naira Marley, lo ti bẹrẹ ipẹjọ tako oṣere tiata, Iyabo Ojo lori ẹsun ibanilorukọjẹ nipa ọrọ to kọ soju opo instagram.

Ninu iwe kan ti agbẹjọro Naira Marley, Olalekan Ojo, kọ ranṣẹ si Iyabo, o ṣalaye pe Arabinrin Ojo ba Naira Marley jẹ́ ninu awọn ọrọ kan to kọ si ori Instagram rẹ ninu oṣu kẹsan-an, 2023.

Agbẹjọro Ojo sọ fun BBC pe Iyabo fẹsun kan Naira Marley pe o fi oogun ati awọn iwa kan ti ko boju mu doju ija kọ oloogbe Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eyan mọ si Mohbad, nigba aye rẹ.

"Awọn nnkan ti Iyabo Ojo kọ nipa onibaara mi, mu ko fojuwina ọpọlọpọ eebu ati ifini ṣe ẹlẹya laarin awujọ."

Naira Marley n beere N500m lọ́wọ́ Iyabo Ojo

Agbẹjọro Olalekan Ojo ṣalaye pe, ọrọ ti Iyabo sọ lo fi n gbiyanju lati sọ pe Naira Marley lo wa nidi gbogbo laasigbo to ba Mohbad nigba aye rẹ, "lẹni ti Naira Marley mu gẹgẹ bi ọmọ ìyá".

Bakan naa lo ni ki Iyabo Ojo tọrọ aforiji lọwọ onibaara rẹ ni gbangba.

Agbẹjọro Ojo ṣalaye pe ẹbẹ fun aforiji naa, ni kii Iyabo fi si oju opo insragram rẹ ko si tun fi sinu iwe iroyin kan ni Naijiria.

O fi kun pe to ba kọ lati ṣe eyi laarin gbedeke ọjọ meje, awọn yoo gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ.

"Ao si beere fun ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira, owo itunu fun Naira Marley."

Aworan iwe ti agbẹjọro Naira Marley ko si Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Others

Aworan iwe ti agbẹjọro Naira Marley ko si Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Others

Aworan iwe ti agbẹjọro Naira Marley ko si Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Others

Naira Marley fi ẹ̀sùn kan Punch Newspaper

Yatọ si Iyabo Ojo, agbẹjọro fun Naira Marley, Olalekan Ojo, tun sọ pe awọn ti fi iwe ẹsun ranṣẹ si iwe iroyin Punch , nitori awọn naa kopa ninu biba onibaara oun l'orukọ jẹ.

O ni Naira Marley yoo gbe ọrọ lọ sile ẹjọ nitori pe wọn fi ọrọ wọn tọka si i pe o lọwọ ninu iku Mohbad.

"Iyabo Ojo ati Punch Newspaper ti gba iwe ẹsun ti wọn, awọn eeyan to ku yoo gba ti wọn naa titi ọjọ Ẹti."