A kò san owó ìtúsílẹ̀ fáwọn àgùnbánirọ̀ tó bọ́ lọ̀wọ̀ ajínigbé - NYSC

Aworan awọn agubanirọ

Oríṣun àwòrán, officialnyscng

Ajọ to n ṣeto agubanirọ lorileede ti sọ pe awọn ko san owo idoola ẹmi kankan lati gba itusilẹ diẹ ninu awọn agunbanirọ wọn kan to ha sọwọ awọn ajinigbe ni Zamfara.

Alukoro ajọ NYSC,Ọgbẹni Eddy Megwa lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lỌjọbọ niluu Abuja.

O ni alaye yi di dandan lẹyin ti iroyin gbode pe ijọba ipinlẹ Akwa Ibom ati awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria kan lo san owo idoola awọn agunbanirọ yi.

Ipinlẹ Akwa Ibom lawọn agunbanirọ yi ti gbera ti wọn si n lọ si Sokoto ki wọn to ko sọwọ awọn agunbanirọ.

O ni ''titu awọn agunbanirọ yi silẹ ko sẹyin igbiyanju awọn eleto aabo ati oṣiṣẹ NYSC''

O ni ''bẹẹ naa lo ṣe pataki lati laaye araalu pe ko si ijọba ipinlẹ kankan,ọlọdani tabi ileeṣẹ ijọba to san owo kankan gẹgẹ bi owo idoola ki wọn to tu wọn silẹ''

Atẹjade yi fikun pe kaakiri lawn ti n ri nọmba akanti ati orukọ awọn ti wọn ni ki awọn araalu maa san owo idoola si ki wọn baa le tu awọn agunbanirọ to ku silẹ.

''Awọn onjibiti lo n lo iṣẹlẹ yi lati pe fun dida owo idoola lọna ati lu awọn eeyan ni gbajuẹ.Ohun iwuri lo jẹ lati mọ pe NYSC ti ribi gba itusilẹ awọn mẹrin ninu awọn agunbanirọ yi lae san owo kankan''

Nigba wo ni wọn ji awọn agunbanirọ yi gbe?

Ọjọ Kejidinlogun Oṣu Kẹjọ ni awọn agunbanirọ yi ko si pampẹ awọn ajinigbe wọnyi.

Wọn n bọ lati Akwa Ibom ni lati lọ bẹrẹ eto isinru wọn ni Sokoto.

Zamfara ni wọn ti ko sọwọ awọn olubi.

Nigba ti wn ko sọwọn awọn ajinigbe, mẹta ninu awọn agunbanirọ yi ribi moribọ ninu awọn mọkanla to wa ninu ọkọ.

O ṣẹku agunbanirọ meje pẹlu dirẹba ọkọ to fi pe eeyan mẹjọ.

Lati igba naa ni awọn agbofinro ,obi ati ijọba ipinlẹ Akwa Ibom ti n gbiyanju lati gba itusilẹ awọn agunbanirọ yi.

Ẹni akọkọ ti wọn ribi doola kuro lahamọ ni ọjọ Kini oṣu Kẹsan.

Logunjọ Oṣu Kẹsan, obinrin mii ninu awọn ti wn jigbe ribi gba itusilẹ gẹgẹ bi NYSC ti ṣe sọ.

Lọwọlọwọ NYSC laan ti ri eeyan mẹrinb gba silẹ lapapọ tawn ko san owo to si ṣẹku eeyan mẹrin mii sọwọ awọn ajinigbe.

Itusilẹ lọwọ ajinigbe ki waye lai ṣe pe eeyan san owo idoola

Ọrọ boya awọn eeyan n san owo idoola abi wọn kii san jẹnkan ti awn agbofinro ati ọmọ Naijiria a maa ba ara wọn jiyan si lọpọ igba.

Idi si ni pe ẹri pupọ wa wi pe awọn eeyan kiiribi bọ lọwọ awọn ajinigbe yi bi kii ṣe pe awọn mọlẹbi wọn ba san owo idoola.

Yala awọn arinrinajo ti wọn ko ninu ọkọ reluwe ni Kaduna ni tabi awọn akẹkọọ ileẹkọ, a ti ri bẹẹ la si ti gbọ iroyin lẹnu awọn ti wn tu silẹ wi pe owo lo yanju ọrọ wọn.

Ajọ NYSC nikan kọ lo n koju ipenija ijingbe yi bi kii ṣe pẹ ọpọ eeyan ni Naijiria .

Alukoro NYSC sọ pe awọn ko le tori ijingbe yi s pe kawọn wọgile eto agunbanirọ nitori ijingbe n waye nibi ti awọn eeyan ko ti lọ sinru.

Amọ Eddy Megwa sọ pe awọn ko dakẹ lati maa fi ikilọ sita fawọn agunbaniro to ba n ri n loju ọna.

''A ti sọ fun wọn pe ti ilẹ ba ti n ṣu ni paapa ti ago mẹfa ba ti lu kiwn ma ṣe tẹsiwaju pẹlu irinajo wọn.A o ni dakẹ lati maa gbawọn ni imọran yi.''