Soun Ogbomoso bẹ̀rẹ̀ ètò àti gbọ̀pá àṣẹ, amòfin àgbà kan sọ ìhà tí òfin kọ síi

Oba Ghandi Olaoye

Oríṣun àwòrán, Free world Tv/BBC

Gbigbe igbesẹ lori ẹjọ to ba n lọ lọwọ nileẹjọ ni wọn ti juwe bi ọkan lara awọn iwa ibajẹ ti ijọba hu julọ lorilẹede Naijiria.

Agbẹjọro agba kan ni Naijiria, Amofin Yomi Aliu (SAN) , lo so eyi ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lọjọ Ẹti lori pe ijọba ipinlẹ Oyo fẹẹ fun Soun Ogbomoso ni ọpa aṣẹ lai ro ti ẹjọ to wa nile ẹjọ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ karundinlogun, oṣu Kejila, ni Soun tuntun naa, Ghandi Olaoye, bẹrẹ eto ayẹyẹ igbade, eyi ti yoo wa sopin ni ọjọ Isẹgun , ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila ti Gomina Seyi Makinde yoo gbe ọpa aṣẹ fun un.

Oriṣiriṣi eto lo si ti n waye laarin awọn ọmọ ilu Ogbomoso ni imurasilẹ fun ọba wọn tuntun.

Amofin Aliu wi pe ko yẹ ki ijọba o maa ṣe ohunkohun lori ẹjọ to ba wa niwaju adajọ, paapaa julọ ọrọ oye jijẹ.

“Aṣiṣe gbaa ni kijọba o fun ọba ni ọpa aṣẹ nigba ti ẹjọ ba wa nile ẹjọ.

“Ti ẹjọ ba n lọ lọwọ, ti wọn ba ni ọba o gbọdọ j'oye, t'ọba bẹẹ ba j'oye, o tumọ si pe ofuutufẹẹtẹ, aasa ti o ni kanhun ni.

O ni ọba to ba gba iru ade bẹẹ kan dunra rẹ ninu lasan ni, to fun awọn eyan lounjẹ ni.

“Ẹrin aarọ, ẹkun alẹ ni, tiru ọba bẹẹ ba joye.

Amofin Aliu ṣalaye pe iru nnkan bayii ti ṣẹlẹ ri ni ilu Igbajọ, o ti ṣẹlẹ ni Ifon-Osun, ti wọn rẹrin laarọ ti wọn sunkun lalẹ.

“Ọba kan tilẹ binu gbẹmi ara rẹ.”

O ni, agbẹjọro to ba wa ni odikeji yoo maa rẹrin ni, tori o mọ pe ofo ni gbogbo igbesẹ naa, pe o kan n dawọ idunnu ni.

“Ti ẹjọ ba wa nileẹjọ, ẹni to ba ni ọpọlọ to si loye o nii de bẹ."

Ki ni ohun to ṣẹlẹ sẹyin ni ile ẹjọ?

Oba Ghandi Olaoye
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to wa nilu Ogbomoso gbe idajọ kalẹ pe, ki Ọba Ghandi Olaoye o fi ori itẹ silẹ ki wọn si bẹrẹ eto iyansipo ọba miran.

Ninu idajọ rẹ lori ẹjọ ti Ọmọọba Kabir Olaoye pe tako gomina ipinlẹ Oyo ati awọn mọkanla miran, Onidajọ Kareem Adedokun wi pe ọna ti wọn gba yan Ghandi Olaoye gẹgẹ bi ọba ni ko tọna, ‘ko lẹsẹ n'lẹ, to si ja si ofo’.

Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ Oyo o pada sile ẹjọ naa lati beere fun idaduro titẹle aṣẹ ile ẹjọ giga naa titi ti igbẹjọ yoo fi waye nile ẹjọ kotẹmilọrun.

Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn ,oṣu Kọkanla ni Onidajọ Kareem Adedokun, lori ẹjọ HOG/27/2022, paa laṣẹ pe gbogbo awọn to nii ṣe pẹlu ẹjọ naa ko gbọdọ gbe igbesẹ tuntun to yatọ si ti atẹyinwa titi di akoko ti idajọ yoo waye nileẹjọ kotẹmilọrun.

Ẹwẹ, adajọ yi kan naa loti wi ṣaaju lọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ninu ẹjọ kan ti Ọmọọba Taofeeq Olaoye pe tako iyansipo Ọba Ghandi Olaoye pe iyansipo naa tẹle ilana to tọ ati eyi to yẹ.