Mọ̀ síi nípa àwon Orí Adé Soun tí ìlú Ogbomọṣo tó ti jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀....

Aafin Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, @Oyo

Láti ana, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan an, ọdun 2023 ti wọn ti fi Oba Afolabi Ghandi Olawoye, Orumogege keji jẹ ni awọn eeyan ti n bèèrè láti mọ sii nipa awọn alade to ti jẹ sẹyin bii Soun ni ilu Ogbomoso to wa ni ipinlẹ Oyo ni Naijiria.

Awọn Oba to ti jẹ naa ni yii ni ṣisẹ n tẹle pẹlu iye ọdun ti wọn lo lori apere Baba wọn:

1. OBA OLABANJO OGUNLOLA OGUNDIRAN 1659-1714

2. OBA ERINSABA ALAMU JOGIORO 1714-1770

3. OBA IKUMOYEDE AJAO 1770- 1797

4. OBA TOYEJE AKANNI 1797-1825: O tun jẹ Aare Ona Kakanfo gbogob ilẹ̀ Yoruba nigba naa.

5. OBA JAIYEOLA ARE AROLOFIN ALAO 1840-1842

6. OBA IDOWU BOLANTA ADIGUN 1842-1845

7. OBA OGUNLABI ODUNARO 1845-1860

8. OBA OJO ABURUMAKU ADIO 1860-1869 Oun naa jẹ Aare Ona Kakanfo gbogbo ilẹ Yoruba nigba naa.

9. OBA GBAGUNGBOYE AJAMASA AJAGUNGBADE 1 1869-1871

10. OBA OLAOYE ATANDA ORUMOGEGE 1871-1901

11. OBA MAJENGBASAN ELEPO 1 1901-1907

12. OBA ADEGOKE ATANDA LAYODE 1 1908-1914

13. OBA ITABIYI OLANREWAJU ANDE 1914-1916

14. OBA BELLO AFOLABI OYEWUMI AJAGUNGBADE 11 1916-1940

15. OBA LAWANI OKE LANIPEKUN 1944-1952

16.OBA OLATUNJI ALAO ELEPO 11 1952-1966

17. OBA OLAJIDE OLAYODE 11 1966-1969

18. OBA SALAMI AJIBOYE ITABIYI 1972-1973

19.OBA OLADUNNI OYEWUMI AJAGUNGBADE 111 1973- 2022.

20. OBA AFOLABI OLAOYE GHANDI ORUMOGEGE II bẹrẹ láti ọdun 2023 titi di igba ti yoo lọ ba awọn baba nla rẹ.

Ìdàgbàsókè tó lóòrìn máa wọ Ogbomoso láìpẹ́, ìgbà ọ̀tun dé - Soun tuntun

Soun Ogbomoso, Olaoye Ghandi
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2023 yii letutu ọjọ meje ti Ṣọun tuntun, Ọba Ghandi Afọlabi Ọlaoye (Orumọgẹgẹ Kẹta), ṣe ni ipebi pe.

Ni bayii, ọba tuntun naa ti jade kuro ni ipẹbi gẹgẹ bii aṣa ilu Ogbomọṣọ.

Ọba Afolabi Olaoye lo rin irin ọla lati ile iwe Girama ti ilẹ Ogbomoso, (Ogbomoso High School) titi de aarin gbungbun Ogbomoso Taki ti wọn si dari sii aafin Ogbomoso to wa ni agbegbe Ọja Igbo nigboro ilu Ogbomoso

Lẹyin eyi ni Ọba Afolabi Olaoye wọ inu Abata lọ nibi ti awọn etutu ati adura fun Ọba naa ti waye.

Lẹyin to wọ inu aafin lawọn eto adura waye laarin awọn ẹlẹsin-jẹsin gbogbo.

Lara awọn ti o lewaju eto ọhun ni pasitọ Gbile Akanni, lati ilu Gboko to si tun jẹ ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ to fi ipinlẹ Benue ṣe ibugbe, ti Ọgbẹni Gbenjo Laolu si lewaju orin iyin.

Ninu ọrọ akọsọ rẹ, Ṣọun ti ilẹ Ogbomoso, Ọba Afolabi Olaoye Orumogege Kẹta rọ awọn ti wọn jọ dupo ọhun lati fọwọsowopọ pẹlu oun ki ilu Ogbomoso le gun oke agba.

O ni pẹlu bi oun ti di Ọba bayii orisirisi ile iṣẹ ni yoo wọ ilu Ogbomoso wa, ti idagbasoke naa yoo si tẹlẹ.

Soun ti ilẹ Ogbomoso ṣeleri lati ko gbogbo eeyan mọra kí idagbasoke to loorin lè fìdí mulẹ niluu naa.

Soun Ogbomoso ti jáde kúrò ní Ipẹ̀bí, Kabiesi Olaoye Ghandi ti wà lọ́nà ààfin Ogbomoso

Soun Ogbomoso
Soun Ogbomoso
Soun Ogbomoso
Skip Facebook post, 1
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post, 1

Kabiesi, Oba Olaoye Afolabi Ghandi ti jade kuro ni Ipẹbi lẹyin ọjọ meje to ti wa nibẹ to ti lọ kọ siwaju sii nipa aṣa, iṣe ati iṣẹṣe Oodua ti o si tun ti lọ gbadura pe ki asiko rẹ tu gbogbo awọn eeyan Ogbomoso lara bayii

Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, bbc

Skip Facebook post, 2
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post, 2

Oba Olaoye Ghandi ti wa lọna aafin Ogbomoso bayii nibi ti yoo ti sóró akókó pẹlu awọn eeyan ilu Ogbomoso.

Òní lòníì ń jẹ́ tí Oba Ghandi Olaoye yóò jáde ní ìpèbí

Soun Ogbomoso

Ọba Afolabi Ghandi Olaoye yoo jade ni ipẹbi loni lẹyin ọjọ meje.

Ọpọ ero ti wa ni ikalẹ lati foju ri Soun ti ilẹ Ogbomoso tuntun: Ọba Afolabi Ghandi Olaoye, Orumogege kẹta, Soun lẹyin ọjọ meje ti o ti wa ni ipẹbi.

Eto Ikije ni ayẹyẹ to rọ mọ fifi oju Ọba tuntun hàn awọn ara ilu paapaa julọ Soun ti ilẹ Ogbomoso.

Ninu eto Ikije yii ni Ọba Afolabi Ghandi Olaoye yoo ti gbadura fun ilọsiwaju ilu ati awọn ti o n jọba lé lori.

Bawo ni eto naa yoo ṣe lọ?

Ọba Afolabi Ghandi Olaoye yoo jade ni ipẹbi loni lẹyin ọjọ meje

Ilẹ iṣẹ BBC Yoruba ri i gbo wi pe, Soun ti ilẹ Ogbomoso tuntun, Ọba Afolabi Ghandi Olaoye, Orumogege kẹta ni awọn ara ilu yoo lọ pade ni abawole ilu Ogbomoso.

Awọn ara ilu Ogbomoso yoo sì jọ kọwọrin pẹlu Oba Soun tuntun titi ti yoo fi wọ Aafin ti yoo si gbadura fun ilu ati awọn ti o n jọba le lori.

Eto Ikije jẹ eto pataki nilẹ Ogbomoso nigba kigba ti Ọba tuntun bá jẹ.

Ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni awọn Afobajẹ ilu Ogbomoso fi Ọba Afolabi Ghandi Olaoye jẹ Soun ti ilẹ Ogbomoso tuntun.