Wo bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ẹ̀rin ṣe eré ìdárayá

Àkọlé fídíò, Wo bí àwọn ṣé ń fí ẹrin rìn ṣé ère ìdárayá

Ẹrin kee kee! Njẹ ṣe ẹrin ni ogun aisan gbogbo?

Njẹ ẹ mọ pe ẹgbẹ́ arẹrin wà?

Dokita Madan Kataria ṣalaye pe bi a ṣe ṣeda ẹgbẹ arẹrin niyẹn. O ni inu ọpọ awọn eeyan o dun nitori wọn n wa idunnu ninu aye .

"A o le yi aye pada ni ọjọ kan ṣoṣo. Ṣugbọn nnkan ti a le ṣe ni, a le yi aye to wa lọkan wa pada.

O tẹsiwaju pe bi awọn ṣe n fi ẹrin yí aye pada lo jẹ ohun idunnu.

Ẹgbẹ ẹlẹrin

Kataria ni ẹgbẹ Arẹrin akọkọ bẹrẹ nilu Mumbai lọdun 1995 lati ṣe ipolongo anfani rirẹrin lori ilera awọn eeyan.

"Inu mi dun gidi lati ri eniyan to le ni ẹgbẹfa ni papa isere nilu Mumbai.

"A darapọ mọ iwọde alafia kan. Gbogbo eeyan bu sẹrin ti a si fi ẹrin ati ifẹ ranṣẹ si gbogbo eeyan lagbaye.

"Ọjọ ẹrin ti agbaye bere ni oṣu kini ọdun 1998 ti wọn si ṣe ayeye rẹ kaakiri agbaye ni oṣu karun."

Anfani wo ni ẹrin ni lori ilera?

Dokita Madan Kataria ni bi awọn ṣe rí ẹni ti inu rẹ dun, ti ara rẹ ya, ọpọlọ re o mọ iyatọ nítorí pe o n rẹrin.

"Rirẹrin jẹ ere idaraya ti o ni agbara lọwọ, lati din wahala ku.

Lati mu ara le koko ati lati jẹ ki gbogbo ẹya to wa ninu ara ṣiṣẹ yege.

"Ọpọ ti darapọ mọ ẹgbẹ arẹrin ni India, ti a si n ṣeda rẹ ni awọn orilẹede miiran.

"Eyi ti n di ẹgbẹ arẹrin nla kaakari agbaye."