Alhaji Kabir Alayande Ere Asalatu: Iṣẹ́ olọgun ló wù mí ṣe àmọ́ kádàrá ló sọ mí di olórin
Ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ohun orin Alhaji Kabir Alayande tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Ere Asalatu tó jẹ́ gbajúgbajà olórin Mùsùlùmí.
BBC Yorùbá kàn sí Ere Asalatu láti bá a sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò rẹ̀ nínú iṣẹ́ orin àti àwọn ohun tó sun dé ìdí orin kíkọ.
Ere Asalatu ní láti kékeré ni òun ti ní ẹ̀bùn orin kíkọ àti pé ìdílé àyàn ni wọ́n bí òun sí nítorí náà orin kíkọ kìí ṣe àjòjì sí òun.
Ó ní òun wo ọ̀nà láti mú àyípapdà ọ̀tun bá orin Islam ni òun ṣe gbé orin òun gba ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí òun ń gbà kọ orin òun.
Bi orin kikọ ṣe di nnkan nla mọ mi lọwọ

Oríṣun àwòrán, Ere Asalatu
Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò mọ̀ wí pé orin náà máa di nǹkan ńlá fún òun, ó ní òun ṣáà kọ orin náà pé kí òun kàn ṣe nǹkan.
Mo fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ wí pé tí ènìyàn bá ń tẹ̀lé Ọlọ́run bó ṣe tọ́, èrè púpọ̀ wà níbẹ̀ fún-un láti jẹ ni òun fi forí orin òun àkọ́kọ́ sọ "Ere Asalatu".
Alayande sọ síwájú pé iṣẹ́ ológun gangan ni ó wu òun láti yàn láàyò ṣùgbọ́n òun gbà pé kádàrá ẹ̀dá kò ní tàsé àti pé nǹkan tí Ọlọ́run bá ti kọ fún ènìyàn kò ní kọjá rẹ̀.
Bákan náà ló tún sọ̀rọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olọrin yòókù bíi àwọn olọrin Fuji.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáṣepọ̀ náà ló ń wáyé láti lè fa ojú àwọn ènìyàn náà sí orin òun àti iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe.
- Ẹ̀mí èèyàn 63 sọnù nílé alájà púpọ̀ kan tí iná t́i ṣẹ́yọ ní South Africa
- Wo àwọn orílẹ̀ èdè tí ààrẹ wọn ti lo kọjá ọgbọ̀n ọdún nípò
- Pa Taiwo Akinkunmi tó ya Àsìá Nàìjíríà dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 87!
- Ààrẹ Gabon, Ali Bongo tí wà ní àhámọ́ àwọn ológun
- 'Ìdí tí mo fi ń kọ́ àwọn ajá òyínbó ní Yorùbá pọ́nbélé tí wọ́n sì lè dáa yín lóhùn rèé'