Ó ti di ènìyàn 73 tó dèrò ọ̀run níbi ìjàmbá iná tó ṣẹ́yọ nílé kan ní South Africa

Ilé tí ìjàmbá iná ti ṣẹ́yọ

Àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi iná kan tó ṣẹ́wọ ní ilé ìgbé kan ní Johannesburg, orílẹ̀ èdè South Africa ti di mẹ́tàléláàdọ́rin báyìí.

Agbẹnusọ àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì Johannesburg, Robert Mulaudzi ní òkú ènìyàn mẹ́tàléláàdọ́rin ni àwọn ti rí yọ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí.

Bákan náà ni ó kéré tán ènìyàn méjìláàdọ́ta mìíràn ló ti farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ìròyìn tún ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló tún ti fẹ̀yìn ṣèṣè níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí èyí sì ṣeéṣe kó wáyé látara bí àwọn ènìyàn ṣe ń gba ojú fèrèsé bẹ́ sílẹ̀ láti móríbọ́ lọ́wọ́ ìjàmbá iná náà.

Àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ní àwọn kò lè sọ pàtó ohun tó fa ìjàmbá iná ní ilé alájà márùn-ún kan ní ìlú ọ̀hún.

Ìgbìyànjú láti dóòlà àwọn ènìyàn tọ hà sínú ìjàmbá iná náà ṣì ń lọ lọ́wọ́.

Mulaudzi sọ fún ikọ̀ ìròyìn BBC pé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ń gbìyànjú láti dóòlà àwọn olùgbé ilé náà.

Ààrẹ South Africa, Cyril Ramaphosa nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìjàmbá iná náà ní àdánù ńlá ni ìjàmbá náà jẹ́ fún orílẹ̀ èdè àwọn.

Ramaphosa ní gbogbo àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn ni àwọn bá kẹ́dùn àti pé gbogbo ènìyàn ènìyàn lọ gbọ́dọ̀ dìde sí àwọn tí ìjàmbá ọ̀hún kàn.

Ó ní òun gbèrò pé tí àbọ̀ ìwádìí sí ohun tó ṣokùnfà iná náà yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn àti ìlú láti dènà irufẹ́ ìjàmbá bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló tò sí iwájú ibi tí ìjàmbá náà ti wáyé tí wọ́n sì ń bèèrè nípa àwọn ẹbí wọn tó ń gbé ilé náà.

Ẹ̀mí èèyàn 63 sọnù nílé alájà púpọ̀ kan tí iná t́i ṣẹ́yọ ní South Africa

South Africa fire

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan, eeyan mẹtalelọgọta lo ti jade laye bayii, nigba ti ogoji eeyan mii farapa yanayana lẹyin ina to ṣẹyọ ninu ile alaja pupọ kan niluu Johannesburg, ni South Africa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajwiri ni Johannesburg, Robert Mulaudzi sọ pe agbegbe ti awọn ileeṣẹ pọ si ni ina ọhun ti ṣẹyọ, awọn si ti ri oku eeyan mẹtalelọgọta yọ.

Iroyin ni ọmọ kekere kan wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, Mulaudzi sọ pe ile naa jẹ ibi ti awọn alainilelori n gbe, bo tilẹ jẹ pe wọn ko gba aṣẹ lati maa gbe ile ọhun lọwọ ijọba.

Awọn oṣojumikoro sọ pe iye eeyan to n gbe ninu ile naa to igba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ileeṣẹ iroyin News24 ti orilẹ-ede South Africa sọ pe ko si ẹni to tii le sọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Awọn alaṣẹ ni awọn ti n ṣaṣeyọri lọna ati pa ina ọhun, ṣugbọn eefin rẹ ti gba gbogbo adugbo, eyii ti awọn eeyan le ri lati okere.

Mulaudzi sọ siwaju si pe o ṣeeṣe ki iye awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ju iye awọn to ti ku bayii.

Ṣugbọn o fi kun pe akitiyan ṣi n lọ lọwọ lati rẹyin ina ọhun ati lati doola ẹmi ọpọ eeyan nibẹ.