Pa Taiwo Akinkunmi tó ya Àsìá Nàìjíríà dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 87!

Pa Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Akinkunmi Akinwumi Samuel/Facebook

Iroyin ti jade wipe Alagba Taiwo Akinkunmi (O.F.R), arakunrin to ṣe ọṣọ asia orilẹede Naijiria ti jade laye.

Ọmọ rẹ ọkunrin, Akinkunmi Akinwumi Samuel lo ṣe ikede naa loju opo Facebook rẹ.

O kọ wipe: “Ajo laye lotitọ; Mo lee sọ dajudaju wipe o gbe igbe aye to laami laaka.

Sun re o! Baba mi! Alagba Michael Taiwo Akinkunmi (O.F.R). Akinkanju ọkunrin ti lọọ!”

Ohun to yẹ koo mọ nipa Pa Taiwo Akinkunmi

Pa Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ilu Owu ni Abeokuta, ipinlẹ Ogun ni wọn ti bi Alagba Akinkunmi ni ọjọ kẹwa oṣu karun ọdun 1936.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ Baptist Day Secondary School ni Ibadan bẹẹ si ni o ka ẹkọ Girama ni Ibadan Grammar School.

O kọkọ gba iṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba ni ọfiisi ijọba, “Secretariat Ibadan”.

Pa Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Akinkunmi Akinwumi Samuel/Facebook

Bawo ni Asia Akinkunmi ṣe gbegba oroke ninu eeyan 2000?

Asia Naijiria

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iru asia to wa nilẹ tẹlẹ jẹ eyi to ni awọ funfun gbawuya pẹlu ila tẹẹrẹ alawọ ewe meji lẹgbẹgbẹ rẹ, ami oorun pupa pẹlu itansan oorun to n han lara awọ funfun naa.

Nigba to ya, igbimọ ti wọn gbe akanṣe iṣẹ naa fun yọ oorun naa kuro lara asia ọhun.

Agbejade ti Akinkunmi ni wọn mu nitori bo ṣe da yatọ ati itumọ ara ọtọ to gbe dani – Awọ ewe tumọ si igbo aginju ati ilọrọ yanturu ti Eleduwa fi ta orilẹede naa lọrẹ, nigba ti awọ funfun to wa nibẹ tumọ si alafia.

Pa Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Akinkunmi Akinwumi Samuel/Facebook

Igba akọkọ ti wọn gbe asia naa ro ni ọjọ ti Naijiria gba ominira gangan (Ọjọ kinni Oṣu Kẹwa, Ọdun 1960).

Iroyin ni iye owo ti ijọba san fun Taiwo Akinkunmi nigba naa lọhun fun iṣẹ to ṣe yii ni Ọgọrun pọun nigba ti wọn yan iṣẹ tirẹ layo.

Bakan naa, ijọba ti fi oye O.F.R (Order of Federal Republic) da a lọla lasiko ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan.

Ẹwẹ, Alagba Taiwo akinkunmi jẹ ẹni ti awọn ọmọ Naijiria yẹ si gidi gan ti wọn si maa jẹ ọrọ rẹ lẹnu pe o yẹ ki ijọba da a lọla gidi gan nigba aye rẹ.

Pa Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Akinkunmi Akinwumi Samuel/Facebook