Èèyàn méjì lọ ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n rì sínú odò ní ìpínlẹ Ogun

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọjọ buruku esu gbomi mu lo jẹ fun awọn ara ijọ Cherubim ati Seraphim ni agbegbe Onikoko ni Itori, lẹyin ti awọn ọmọ ijọ wọn meji ri sinu omi ni agbegbe naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Omolola Odutola lo fi iroyin naa lede, fun awọn ara ilu lati maa ṣọra ṣe ni asiko yii.

Arakunrin Adebayo Adeosun ni wọn lo lọ si agọ ọlọpaa lati lọ ro ti ẹnu rẹ lorii bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

Bawo ni awọn meji ṣe ri sinu omi?

Arakunrin naa sọ fun awọn ọlọpaa pe awọn ọdọ bii meje ni wọn wa lati ilu Eko ni Ọjọ Kẹtadinlọgbọn, Osu Kẹjọ fun ayẹyẹ ikọle ni ile ijọsin naa.

Awọn meje yii ni wọn kuro ni ile ijọsin ti wọn si gba odo lọ lati lọ luwẹ, amọ ti meji ninu wọn si ri sinu omi ọhun.

Awọn meji ti wọn ri sinu omi ọhun ni wọn pe orukọ wọn ni Femi Akinola, ẹni ọdun mejilelọgbọn to wa lati agbegbe Odo Eran, Itire ni ipinlẹ Eko ati Tunde Falade to je ẹni ọdun marundinlogoji naa, ti o wa lati agbegbe Kola Alagbado ni ipinlẹ Eko.

Awọn eniyan sugba lati doola ẹmi wọn, ti wọn si gbe wọn lọ si ileewosan ni Itori, amọ ẹpa ko boro mọ, dokita kede pe wọn ti jade laye.

Ọga ọlọpaa ni agbegbe naa, Olayemi Jacob lo ko awọn isọngbe rẹ lọ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ, ti wọn si ni ko si ohun to jọ ohun ikọkọ ninu iṣelẹ naa.

Nibayii, wọn ti gbe oku wọn lọ si ile igbokusi ni ileewosan ti wọn ti jadu ẹmi wọn.

Kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ba awọn ara, ọrẹ ati ojulumọ awọn to doloogbe naa kẹdun, to fi mọ ile ijọsin naa.

Bakan naa ni wọn fi da awọn ara ilu loju wi pe awọn yoo bẹrẹ idanilẹkọ lati la awọn eniyan lọyẹ, ki iru iṣẹlẹ naa ma baa tun waye mọ.

Kọmisọna wa kilọ fun awọn ọdọ ki wọn maa fi ara balẹ, ki wọn si maa sọra lati lọ wẹ ni odo ni igba ti ọwọ omi ba n ru soke.