Ilé ẹjó fún Ìyá Àbẹ̀bí Olórìsà Osun ní béélì

Oríṣun àwòrán, Others
Ile Ẹjọ Majisireti kan ni Ilọrin, olu ilu ipinle Kwara lọjọ Isegun fun awon onisese Meji kan ni beeli,
Abebi Efunsetan Yakubu, ti ọpọ mọ si Olorisa ati Obalowu Jimoh ni ile ẹjọ gba beeli wọn nibi igbẹjọ rẹ.
Wọn fi Olorisa si atimole pẹlu akẹgbẹ rẹ, Ọbalowu Jimoh latari ẹsun kan ti gbajugbaja aṣiwaju ẹsin Islam kan, Alfa Nna Okutagidi pe tako wọn pe wọn n ba oun lorukọ jẹ.
Gẹgẹ bi ose wa ni inu iwe awon ọlọpaa si ile ẹjọ naa, (FIR), Alfa Okutagidi naa sọ wi pe ohun rii lori ayelujara ti obinrin naa sọ pe ohun ran iyawo ohun akọkọ lọwọ nipa sise etutu ki o to bi ọmọ ati leyin ti o bi ọmọ tan, ni nkan bi ọdun diẹ sẹyin.
Ọjọ mọkandinlọgbọn ni awọn afurasi naa ti lo ninu ahamọ lọgba ẹwọn.
Olupẹj̀ sọ pe awn iwadi ti awọn ṣe fihan pe Iya Abebi (Olorisa) ati Obalowu Jimoh gbimọ pọ lati ba Okutagidi loruko je ati lati da modaru sile ni awujo.
Leyin awuyewuye awon agbẹjọro fun igun mejeeji, Majisireti Muhammed Adam gba lati fun awon afurasi mejeeji naa ni beeli.
O so wi pe won ni eto si ominira won labẹ ofin.
Ile ẹjọ naa wa sun igbẹjọ si Ojo kerindinlogbon osu Ogun (osu keewa) odun ti awa yi.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Lọjọ kẹta oṣu kẹjọ ni Ile ẹjọ Majisireti kan ni Ilọrin, ti paṣẹ pe ki wọn fi arabinrin, Abẹbi Ẹfunsetan Yakubu ti inagijẹ rẹ n jẹ Olorisa si atimọle lori ẹsun ibanikorukọjẹ ti won fi kan an.
Ẹsun ibanilorukọ jẹ yi niiṣe pẹlu fidio kan to ṣe nibi to ti tabuku Alfa Tonile Okutagidi ati baba rẹ oloogbe Sheikh Awwal Okutagidi to ni wọn wa ṣe iṣẹ aajo lọdọ ohun.
Abẹbi Efunsetan nikan kọ ni adajọ ni ko wa latimọle fun igba diẹ naa.
Arakunrin Obalowu Jimoh to jẹ ẹni to ya fọnran fidio naa to si ṣe alabapin rẹ soju opo ayelujara yoo wa ni atimọle fun igba diẹ titi ti adajọ yoo fi gbẹjọ wọn ni pẹrẹwu.
Ọrọ yi lohun ṣe pẹlu fakinfa to n waye laarin awọn ẹlẹsin ibilẹ ati awọn kan ninu awọn musulumi ni ilu Ilorin.
Bi a ko ba gbagbe ọrọ to fẹ jọ mọ ija ẹsin yi ti n fẹ maa da omi alaafia ru nilu Ilorin nigba tawọn ẹlẹsin Islam lawọn ko fẹ ẹbọ ṣiṣe ni Ilu Ilorin tawọn ẹlẹsin ibilẹ si sọ pe awọn lẹtọ labẹ ofin Naijiri lati ṣe eyikeyi ẹsin to wu awọn















