Àwọn afọbajẹ Iseyin kéde Sefiu Oyebola gẹ́gẹ́ bíi Aseyin tuntun

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn afọbajẹ ilu Isẹyin ti kede ọba titun fun ipo Asẹyin ti ilu Isẹyin.
Ọmọọba Ṣẹfiu Oyebọla ni wọn kede gẹgẹbi Asẹyin tuntun.
Awọn afọbajẹ ilu Iṣẹyin kede Oyebọla gẹgẹbi ẹni ti yoo bọ sipo ọba ilu Isẹyin ni aafin asẹyin lọjọ Iṣẹgun.
Gẹgẹbi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, awọn afọbajẹ mẹwaa lo dibo yan Ọmọọba Oyebọla sori apere Ọba ilu naa.
Ẹni ọdun mẹtalelaadọta ni Ọmọọba Ṣẹfiu Oyebọla.
Awọn ọmọọba mejila lo jade du ipo asẹyin lẹyin ti Asẹyin ana, Ọba Ganiyy Adekunlẹ Ajinasẹ.
O ti pe dun kan bayii ti Asẹyin Adekunle Ajinasẹ waja ni ile iwosan nla UCH nilu Ibadan.
Ọdun marundinlogun lo si lo lori oye ko to wọ kaa ilẹ sun.
Nibayii, ohun to kan ni fun awọn afọbajẹ lati fi orukọ Asẹyin tuntun ti wọn yan naa ṣọwọ si gomina Seyi Makinde ati ijọba ipinlẹ Ọyọ fun igbwọle ati lati gba ọpa aṣẹ.














